Oluṣẹyẹ Iyiade, Akure
Ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC loriẹ-ede yii ni wọn peju peṣẹ siluu Igbotako, nijọba ibilẹ Okitipupa, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to kọja, nibi ti gbajugbaja oniṣowo ni, Dokita Jimoh Ibrahim, ti kede ipinnu rẹ pe oun ko ba wọn ṣe ẹgbẹ PDP mọ, o ni oun ti darapọ mọ ẹgbẹ APC to n ṣejọba ipinlẹ Ondo lọwọ lati ọjọ naa lọ.
Ojulowo ọmọ ẹgbẹ PDP lọkunrin agbẹjọro ọhun tẹlẹ, ni kete ti Gomina ana nipinlẹ Ondo, Dokita Oluṣẹgun Mimiko ti sa kuro ninu ẹgbẹ Labour to wa, to si lọọ darapọ mọ PDP ni nnkan ko ti lọ deedee mọ laarin awọn mejeeji.
Ninu ẹgbẹ yii kan naa ni Ibrahim ti dije ta ko Eyitayọ Jẹgẹdẹ ti Mimiko fa kalẹ ninu eto idibo gomina to waye lọdun 2016, eyi to ṣokunfa bi ẹgbẹ ọhun ṣe fidi–rẹmi latari ọkan-o-jọkan ẹjọ ti wọn pe ara wọn lori ẹni to yẹ ko dije.
Eto idibo ku bii ọjọ meji pere nile-ẹjọ sẹṣẹ da Jẹgẹdẹ lare, ti adajọ si kede rẹ nigba naa pe oun lẹni to lẹtọọ ati dije lorukọ ẹgbẹ PDP.
Ọrọ to kọkọ ti ẹnu ọkunrin yii jade lẹyin idajọ naa ni pe ko dun oun rara bi wọn ṣe da alatako oun lare, nitori pe ọbẹ ge ọmọ lọwọ, ọmọ sọ ọbẹ nu, ọbẹ ti ṣe ohun to fẹẹ ṣe.
O ni inu oun dun pe erongba oun lori eto idibo to fẹẹ waye naa ti di mimusẹ ki wọn too da Jẹgẹdẹ lare.
Loootọ lọmọ bibi ilu Igbotako ọhun ko duro sibi kan sọ fawọn eeyan pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ PDP, sibẹ, ko ba wọn da sohunkohun lati ọdun bii mẹrin sẹyin, bẹẹ ni ko si fi bo rara pe Gomina to wa lori oye, Arakunrin Rotimi Akeredolu loun n ṣatilẹyin fun.
Idi ree ti ipinnu to ṣe lọjọ Ẹti, Furaidee ọsẹ to kọja ko ṣe fi bẹẹ jọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo loju pẹlu bo ṣe jẹ pe ọpọ wọn lo ti mọ ẹni to n ṣiṣẹ fun tẹlẹ ko too ṣẹṣẹ waa kede erongba rẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ APC.