Wahala ẹgbẹ PDP n le si i,  ajatuka nipade wọn  

Faith Adebọla

Ko ti i jọ pe wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu yoo rodo lọọ mu’mi pẹlu bi awọn agbaagba ẹgbẹ kan ṣe fabinu yọ lori igbesẹ ti ẹgbẹ naa gbe lasiko ipade akanṣe igbimọ amuṣẹṣe wọn to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an, ta a wa yii, lolu-ile ẹgbẹ wọn to wa l’Abuja, nigba ti  Alaga igbimọ alamoojuto ẹgbẹ naa, (Board of trustee) Alaaji Walid Jibrin, kọwe fipo silẹ, pe oun yọnda ipo oun gẹgẹ bii alaga igbimọ awọn agbaagba ẹgbẹ, ti wọn si ti yan Adolphos Wabara, lati ipinlẹ Abia, lati rọpo rẹ gẹgẹ bii Adele.

Ẹgbẹ naa gbe igbesẹ yii lati fi tu awọn eeyan agbegbe Guusu ninu latari bawọn eeyan Guusu ṣe n binu, ti wọn ko si fara mọ bawọn ipo pataki pataki laarin ẹgbẹ naa, bii oludije funpo aarẹ, alaga apapọ ẹgbẹ ṣe sodo siha Ariwa, tawọn eeyan naa si n beere pe ki ipo alaga apapọ ẹgbẹ bọ sọdọ awọn, tọrọ naa si ti di itahun-sira-ẹni ati aawọ laarin ẹgbẹ naa.

Ṣugbọn igbesẹ yii ko ṣetẹwọgba fawọn agbaagba ẹgbẹ naa bii Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, Oloye Bọde George, atawọn mi-in lati iha Guusu, wọn ni bii igba ti wọn p’aja l’ọbọ fawọn eeyan agbegbe Guusu ni igbesẹ yii, awọn o si le fara mọ ọn.

Wike, to sọrọ ṣoki lẹyin ipade naa sọ pe, bii igba ti wọn n yin’gbado sẹyin igba ni ohun to ṣẹlẹ yii, tori ohun toun atawọn eeyan agbegbe oun beere fun yatọ si eyi ti wọn ṣe yii. O tun ni ko sidii meji toun fi n ba Alaga ẹgbẹ wọn, Iyorchia Ayu, ja, to kọja iwa ailadehun rẹ, o ni Ayu funra ẹ ti ṣeleri ko too depo alaga pe ti oludije funpo aarẹ ba fi le wa lati apa Oke-Ọya, oun maa fi ipo alaga silẹ wọọrọwọ ni, ki ẹlomi-in lati Guusu di alaga, lati le mu ki ipindọgba wa laarin ẹgbẹ.

Bakan naa ni Ṣeyi Makinde, sọ pe pẹlu ohun to ṣẹlẹ yii, oun atawọn eeyan oun ko ni i jawọ ninu ilakaka awọn lati jẹ ki ẹgbẹ PDP fi awọn eeyan Guusu si ipo to tọ si wọn, tori tẹni-n-tẹni, takisa ni t’aatan.

Ọrọ naa tilẹ bi Bọde George ninu gidi, wọn ni niṣe ni baba agbalagba to ti figba kan jẹ igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ naa binu jade nipade ọhun, o si sọ pe ohun to waye nipade naa ko bọ si i rara, tori niṣe lawọn eeyan kan fẹẹ maa yan akara jẹ lori awọn eeyan agbegbe Guusu ninu ẹgbẹ PDP.

Ni bayii, a gbọ pe awọn ijoye ẹgbẹ oṣelu naa ti fọwọ si i pe ki Ayu maa ba iṣẹ rẹ lọ, bo tilẹ jẹ pe ara o rọ okun, ara o si ti i rọ adiẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Leave a Reply