Adefunkẹ Adébiyi, Abẹ́òkúta
Aafaa kan to n kọ awọn ọmọ ni keu lagbegbe Imẹdu-nla, ni Mowe, ko sun ile rẹ mọ bayii, ọdọ ẹka to n ri si ifipabanilopọ nipinlẹ Ogun lo wa pẹlu ẹni keji rẹ, Tọliha Sabit. Ọmọ ọdun mẹẹẹdogun to jẹ obinrin lawọn mejeeji fipa ba sun lọjọ kẹẹẹdọgbọn, ọsu kẹjọ, wọn si ti jẹwọ pe loootọ lawọn ṣe bẹẹ.
Ohun ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ fun ALAROYE ni pe ọmọbinrin naa lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Redeemed Camp, ni Mowe, pe Sabit Tọliha fipa ba oun sun ninu ile rẹ laduugbo Imẹdu -nla. O ni ohun to ṣe naa ko dun mọ oun ninu loun ṣe gba ile Aafaa Saheed to n kọ awọn ni keu lọ lati fẹjọ Tọliha sun.
Ṣugbọn nigba ti Aafaa Saheed gbọ ohun to ṣẹlẹ, niṣe lo sọ fun ọmọbinrin naa pe ibasun ti Tọliha ko fun un yẹn ti le doyun lara rẹ o. O ni bi ko ba fẹẹ loyun latari ibalopọ ọhun, ko yaa fara balẹ koun ba a ṣayẹwo ara ẹ.
Ayẹwo to loun fẹẹ ṣe fọmọ ile keu rẹ naa lo di ibalopọ. Alukoro ni ọmọ naa salaye pe Aafaa Saheed ba oun lo pọ, o tun ki kinni kan ṣoṣoro to mu bii abẹ bọ oun loju ara.
Ìnira to lagbara lọmọbinrin yii bẹrẹ si i ri pẹlu agbako ibasun toun nikan ko lọwọ ọkunrin meji yii, ati ti kinni ṣoṣoro ti Aafaa Saheed fi gun un loju ara.
Eyi naa lo jẹ ko lọọ fẹjọ sun ni teṣan, ti wọn fi mu Tọliha ati Aafaa Saheed lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ, to ṣẹṣẹ pari yii, iyẹn ọjọ kẹta lẹyin ti wọn kona fọmọ ọlọmọ. Ileeewosan lọmọ ọhun si wa bayii, to n gba itọju
CP Edward Ajogun lo paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ sẹka to n ri si iwa ti wọn hu yii, bẹẹ lo kilọ fawọn obi pe ki wọn mojuto awọn ọmọ wọn daadaa nitori iru awọn aafaa onikinni ko mọ ẹnikan bii eyi.