Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ara me riyi ri ni ọrọ dokita alabẹrẹ kan, Adio Adeyẹmi jẹ o. Ọkunrin naa si lori laya, o pa ọrẹbinrin rẹ torukọ rẹ n jẹ Ifẹoluwa. Lẹyin to pa aa tan lo lọọ ju oku rẹ sinu igbo. Lẹyin naa lo tun pa iyaale ile kan, Nofisatu Halidu, to si sin oku rẹ sinu ọfiisi rẹ. Wọn ti wa obinrin naa titi, wọn ko ri i, ki wọn too ri i nibi ti dokita onisẹẹbi yii bo o mọ ni ọfiisi rẹ nileewosan Jẹnẹra ilu Kaiama, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ.
ALAROYE gbọ pe akolo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ni Dokita Adio Adeyẹmi Adebọwale wa bayii fawọn ẹsun ti wọn fi kan an yii.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niluu Ilọrin, lo ti ṣalaye pe lẹyin ti awọn olugbe Kaiama, kọ iwe ẹsun si kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara pe ọmọbinrin kan, Nofisat Halidu, dawati ni CP Paul Odama psc Odama psc(+), paṣẹ ki iwadii bẹrẹ loju-ẹsẹ. Eyi lo ṣokunfa bi wọn ṣe lọọ mu Dokita Adio Adeyẹmi Adebọwale, ti wọn ni o ṣeku pa ọrẹbinrin rẹ, Ifẹoluwa, to n gbe ni agbegbe Tankẹ, niluu Ilọrin, to si lọọ sọ oku rẹ sigbo niluu Alapa, lọdun 2021. Wọn pe Dokita Adeyẹmi wa si ipinlẹ Kwara, lati Edo, to wa fun ifọrọwanilẹnuwo.
Ajayi tẹsiwaju pe nigba ti wọn ja ọfiisi Dokita Adeyẹmi nileewosan Jẹnẹra niluu Kaiama, ni wọn tun ba saree kan to fi simẹnti rẹ mọlẹ, nigba ti wọn fọ ọ ni wọn ba oku arabinrin ti wọn ti n wa lọjọ to ti pẹ, iyẹn Nofisat Halidu, ti ọkọ rẹ, Ọgbẹni Halidu, naa wa nibi iṣẹlẹ naa. Ko ti i sẹni to le sọ ohun ti awọn eeyan naa ṣe fun un to fi pa wọn, to si gbe oku alakọọkọ ju sinu igbo, to tun sin ẹlẹẹkeji sinu ọọfiisi rẹ.
Lara awọn ohun ti wọn tun ri nibẹ ni foonu meji ti wọn ba ninu baagi apamọwọ obinrin kan ti wọn ba ninu durọọ Adeyẹmi, baagi apamọwọ obinrin meji, wiigi ti obinrin maa n gbe sori, ibori ati pata obinrin kan.
Eyi lo mu ki ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, ki wọn yọnda dokita naa tori pe o ni awọn ibeere kan ti yoo dahun si ni Kwara lori awọn ohun ti wọn ba ni ọfiisi rẹ. Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara sọ pe ko ni i si aaye fun awọn iwa ọdaran ni Kwara, ki gbogbo awọn ọdaran tete tọwọ ọmọ wọn bọṣọ.