Monisọla Saka
Sababi ire lawọn agbofinro teṣan ọlọpaa Surulere, nipinlẹ Eko, jẹ fun awọn afurasi adigunjale mẹrin kan, Babatunde Ogunyẹmi, ẹni ọdun mejidinlaaadọta (48), Ọlatunde Ayinde, ẹni aadọta ọdun (50), Oludare Oluṣẹgun, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta (49) ati Sunday Ebifega, ẹni ọdun mọkanlelogoji (41) to n ja ṣọọbu kan lọwọ tọwọ fi tẹ wọn. Awọn eeyan to wa nitosi ti kọkọ lu wọn lalubami, nigba ti wọn si n mura lati pa wọn ni awọn ọlọpaa rin sasiko, ni wọn ba doola ẹmi wọn.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Benjamin Hundenyin, ṣalaye pe awọn mẹrin ọhun lawọn eeyan to wa nitosi ti n da dawọ jọ lu lẹyin ti wọn mu wọn nibi ti wọn ti n ko ile itaja igbalode kan lagbegbe Surulere.
O lawọn eeyan adugbo naa ni wọn pe agọ ọlọpaa pe ki wọn tete waa ba awọn da si ọrọ awọn ti wọn n lu ole laduugbo awọn ko too di wahala sawọn lọrun, ṣe ki sobia too degbo, oluganbe la a ke si.
Loju-ẹsẹ lawọn agbofinro naa ti debẹ, iya si ti jẹ awọn araabi kọja afẹnuroyin ki wọn too gba wọn silẹ. Lẹyin ti wọn gba awọn afurasi naa kalẹ lọwọ iku airotẹlẹ ni awọn ọlọpaa waa fi panpẹ ofin gbe wọn.
Hundenyin ni, ” Kamẹra ti kọkọ gbe awọn afurasi yii ri nile itaja yii kan naa lasiko ti wọn n gbiyanju lati ji igo ọti oyinbo kan ti wọn n pe ni Martell Blue swift mẹfa.
Bẹẹ lọkan ninu awọn afurasi yii, Sunday, ti foju bale-ẹjọ ri lọdun 2021 fun ẹsun ṣọọbu jija yii kan naa, ki wọn too tun waa pada lọ sile itaja ọhun lati tun ja wọn lole “.
Alukoro ọlọpaa ni awọn afurasi mẹrẹẹrin ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ ni kete tawọn ba ti pari iwadii. Bakan naa ni Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Abiọdun Alabi, gboṣuba kare fawọn eeyan adugbo naa fun pipe ti wọn pe awọn agbofinro lori ọrọ to le ṣakoba tabi da wahala silẹ ọhun. O waa rọ awọn araalu lati jawọ ninu ṣiṣe idajọ lọwọ ara ẹni nitori pe iwa ọdaran loun naa laaye ara ẹ.