O ma ṣe o! Ọkọ oju omi to danu ẹmi eeyan meji lọ nipinlẹ Kogi

Eeyan meji ni wọn ti pade iku ojiji lẹsẹ-o-gbeji pẹlu bi ọkọ oju omi kan ṣe yi danu niluu Lọkọja, olu ilu ipinlẹ Kogi, lẹyin alagbalugbu omi to gba gbogbo ilu naa kan latari arọọda ojo.

Lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni wọn ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti ọkọ naa n ko awọn ero lọ siluu Ajaokuta, nipinlẹ naa. Oku eeyan meji lawọn omuwẹ ti wọn kan lu odo Ganaja, naa kọkọ ri gbe jade. Ọkan ninu awọn meji ọhun ni ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Abdulfatai Abdulazeez.

Bẹẹ ni wọn o ti i dawọ wiwa awọn yooku naa duro. Odo Ọya ti wọn n pe ni River Niger, ni wọn lo ti kun akunfaya, to si ṣe bẹẹ ya wọ gbogbo oju titi. Eyi mu ko ṣoro fawọn eeyan agbegbe ibẹ lati maa lọ maa bọ, bi ko ṣe ki wọn sọ ọkọ oju omi di eto irinna wọn tuntun.

ALAROYE gbọ pe lasiko tọkọ n gbe awọn ero sọda lati Ganaja lọ si opin Ajaokuta lọhun-un ni ọkọ oju omi naa doju de, ti ko si  le ko awọn ero inu ẹ de ebute ibi ti wọn n lọ. Ohun to mu kọrọ naa buru ni pe aọn eeyan ko si nitosi lati ran wọn lọwọ, nitori ọwọ alẹ to jẹ.

Leave a Reply