Ọlawale Ajao, Ibadan
Kayeefi ni igbesẹ ọhun jẹ loju ọpọ eeyan nigba ti awọn ọdọ kan ṣe iwọde kaakiri igboro Ibadan, ti wọn ni awọn ko fẹ nnkan mi-in ju ki ijọba pa ajọ EFCC rẹ lọ.
EFCC, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission, lajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati kiko owo ijọba tabi owo araalu jẹ lorileede yii.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lawọn ọdọ ọhun ko ara wọn jọ, ti wọn si kegbajare lọọ ba Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ ni sẹkiteriati ijọba ipinlẹ naa.
Bo tilẹ jẹ pe Gomina Makinde tabi aṣoju ijọba rẹ kankan ko jade si awọn eeyan yii, sibẹ, fatafata ni wọn n pariwo pe ki ijọba jọwọ, ba awọn gbe igbesẹ lati lati pa ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ naa rẹ nitori niṣe lawọn oṣiṣẹ ajọ yii n fi iya jẹ awọn, ti wọn si n tẹ ẹtọ awọn loju.
Ọkan ninu awọn olwọde naa to pera ẹ ni Samuel, ṣalaye pe “Awọn EFCC n daamu wa, wọn n mu wa, wọn si n gbe wa lọ si kootu lori ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ, wọn aa ni Yahoo ni wa, gbogbo eeyan naa ni Yahoo loju wọn.
“Emi ti mo n sọrọ yii, ẹnjinnia ni mi, ileeṣẹ kan ni mo n ba ṣiṣẹ, ṣugbọn awọn EFCC mu mi, wọn ni mo n lu awọn eeyan ni jibiti lori ẹrọ ayelujara.
“Ohun to waa buru ju nibẹ ni ọna ti wọn maa n gba mu wa, wọn kan maa n wọ inu ile onile kaakiri. Eyi si lodi sofin ọmọniyan lorileede yii ati kaakiri agbaye nitori wọn n tẹ ẹtọ wa loju pẹlu bi wọn ṣe n waa toju bọ kọrọ yara wa yẹn, ti wọn aa si maa tu inu ile onile bii pe wọn ba oluwarẹ̀ tọju nnkan pamọ sibẹ”.
Awọn ọdọ wọnyi waa rọ ijọba lati ṣatunto ajọ EFCC lọna to jẹ pe wọn yoo maa ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bo ṣe yẹ ki wọn ṣe e, to fi jẹ pe wọn ko ni i maa kọjá ààyè wọn mọ, tabi ki wọn kuku fopin si ajọ naa patapata.
Ọsẹ ta a wa yii naa ni wọn ṣe iru iwọde yii nipinlẹ Delta, nibi ti awọn ọdọ nibẹ naa ti n binu nitori ọna ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ naa n gba mu wọn bíi ẹni mu afurasi ọdaran.
Bi iwọde ti wọn pe ni ‘End SARS’ si ṣe bẹrẹ lọdun to kọja naa ree ti ijọba apapọ fi fagi le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale nilẹ yii, boya wọn yoo ṣe bẹẹ pẹlu awọn EFCC yii lẹnikan ko ti i le sọ