Ọlawale Ajao Ibadan
Gbogbo eeyan lo maa n nifẹẹ si ki awọn ibeji jọ ara wọn. Ṣugbọn iru awọn ibeji bẹẹ ni wọn le royin awọn ipenija to rọ mọ jijọra ti awọn jọra.
Ọkan ninu iru awọn ipenija bẹẹ lo ṣẹlẹ si arẹwa obinrin kan nigboro Ibadan, Adekunle Kẹhinde, ẹni ti afẹsọna Taye, ikeji rẹ, wọ mọra, o ti di mọ obinrin naa tan ko too mọ pe Kẹhinde leyi, ki ṣe Taye ololufẹ oun.
Gẹgẹ bi Kẹhinde, to jẹ ọmọ bibi ilu Ibadan yii ṣe ṣalaye ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ALAROYE nibi ajọdun awọn ibeji agbaye to waye niluu Igboọra, ni ipinlẹ Ọyọ, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, o ni “Ba a ṣe jẹ ibeji yii n jẹ ka ri ojuure awọn eeyan nitori ọpọ eeyan lo fẹran ibeji, ba a ṣe jọ ara wa yii, awọn eeyan maa n ṣi wa mu sira wa nitori wọn o mọ iyatọ laarin wa.
“Nigba ta a wa nileewe, ọrẹkunrin ekeji mi (Taiwo) wa sile wa, o ba di mọ mi, o ro pe emi ni Taiwo, ololufẹ oun. Mo waa ni ki i ṣe iyawo ẹ leleyii o, o waa ni ki n ma binu, oun ro pe Taiwo loun ba nile ni.
“Ti emi ati ikeji mi ba ja, bi eeyan kan ba sọ pe oun fẹẹ pari ija fun wa, ti onitọhun ko ba ṣọra ẹ, niṣe la maa sọ ija yẹn di tiẹ, to jẹ pe oun gan-an lawa mejeeji maa doju ija kọ.”
Kaakiri ilẹ Yoruba lawọn ibeji ti peju pesẹ si papa iṣere Methodist Grammar School, to wa niluu Igboọra, nipinlẹ Ọyọ, fun ajodun awọn ibeji tọdun yii, ti papa iṣere nla ọhun si kun dẹnu, paapaa pẹlu bi gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, pẹlu awọn oloṣelu naa ko ṣe gbẹyin nibẹ.