Nitori ọrọ ti oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar sọ pe ẹni to ba wa lati apa Oke-Ọya lawọn eeyan apa Ariwa n fẹ gẹgẹ bii aarẹ wọn, Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ti ṣapejuwe ọrọ to tẹnu oludije dupo ninu ẹgbẹ wọn yii jade gẹgẹ bii ọrọ rirun, ẹlẹyamẹya ati alanikanjọpọn. O waa ke sawọn ẹgbẹ oṣelu PDP lati bọ sita, ki wọn tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori ọrọ to le da wahala silẹ ti ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Adamawa naa sọ.
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹwaa yii, ni igbakeji aarẹ tẹlẹ ọhun sọrọ ọhun nigba to n dahun ibeere ti agbẹnusọ igbimọ awọn agbaagba apa ilẹ Ariwa, Northern Elders Forun(NEF), Hakeem Baba-Ahmed, n bi i.
Lasiko to n ṣe ifọrọjomitoro-ọrọ pẹlu apapọ ẹgbẹ awọn eeyan agbegbe Ariwa to waye nipinlẹ Kaduna, ni Atiku ti sọ pe, “Mo mọ gbogbo orilẹ-ede yii tinu-tẹyin, mo ti kaakiri tibu-tooro orilẹ-ede yii ri. Mo si lero pe ohun ti awọn eeyan apa Ariwa n fẹ ni eeyan to wa lati apa Oke-Ọya nibi, to tun waa mọ nipa awọn apa ibomi-in lorilẹ-ede yii, to si tun ni ajọṣepọ to gun mọ pẹlu awọn eeyan yooku, ohun tawọn eeyan Ariwa n fẹ niyi. Awọn ara ilẹ Hausa o fẹ oludije lati apa ilẹ Ibo tabi Yoruba, ọmọ apa Ariwa ni wọn n fẹ. Mo duro siwaju yin bayii gẹgẹ bii ogunna gbongbo ilẹ Naijiria lati apa Oke Ọya “.
Nigba to n sọ si ọrọ yii, pẹlu ibinu ni Wike to ba awọn oniroyin sọrọ ni papakọ ofurufu ilu Portharcourt lọjọ Aje, Mọnde, to de pada silẹ yii lati orilẹ-ede Spain, nibi toun atawọn ojugba ẹ nipinlẹ Benue, Ọyọ ati Abia ti lọọ ṣepade fi ni ko da oun loju pe ẹnu Atiku ni gbogbo awọn ọrọ buruku yẹn ti jade niru akoko ti ọrọ oṣelu fẹẹ pin orilẹ-ede yii yẹlẹyẹlẹ. O ni iru igbesẹ ti oludije dupo aarẹ fẹẹ maa gbe yii ni yoo sọ bi yoo ṣe maa ṣe deede pẹlu ẹgbẹ naa nigba to ba de ori oye.
O ni to ba waa jẹ loootọ ni Atiku sọrọ yẹn, a jẹ pe ki i ṣe aṣeju loun atawọn eeyan oun n ṣe nigba tawọn ta ku pe ki alaga apapọ ẹgbẹ awọn, Sẹnetọ Iyorchia Ayu, kọwe fipo silẹ ki aaye le wa fawọn eeyan apa ibomi-in naa lati kopa ninu idari ati idagbasoke ẹgbẹ. Gomina Wike duro lori pe awọn agba ati alaṣẹ ninu ẹgbẹ wọn gbọdọ tete gbe igbesẹ lori ọrọ naa, ki wọn si bẹ awọn ọmọ Naijiria, bi bẹẹ kọ, awọn eeyan maa bẹrẹ si i ri ẹgbẹ wọn bii eyi ti ki i ṣe deede, ti ko si ṣee fọkan tan ni.
Ka ranti pe, nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ ninu ẹgbẹ PDP latigba ti Atiku ti wọle ibo abẹle ẹgbẹ naa, ti Ayu si kọ lati kọwe fipo ẹ silẹ gẹgẹ bii ileri to ṣe pe oun yoo kuro nipo alaga ti ipo aarẹ ba ja mọ awọn eeyan apa Ariwa toun naa ti wa lọwọ.
Latigba naa ni omi alaafia ẹgbẹ wọn o ti toro mọ, ojoojumọ ni ọkan-o-jọkan ina ija si n ru nibẹ.
Eyi to waa buru ju, to si n bi Wike ninu ni wiwọ ti Atiku wọ awọn ẹya Yoruba ati Igbo nilẹ ninu ọrọ to sọ ni Kaduna, Wike ni ko tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ orilẹ-ede yii, ko ma baa fi tiẹ ko ba ti ẹgbẹ lasiko idibo to n bọ lọna.