Awọn ajinigbe ti yọnda awọn agbẹ ti wọn gbe lagbegbe Isẹyin pẹlu miliọnu mẹwaa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ti awọn ajinigbe yinbọn pa ọkan ninu awọn agbẹ ti wọn ji gbe ninu oko ti wọn ti n ṣiṣẹ nitosi ilu Isẹyin, ni ipinlẹ Ọyọ, Ọlọrun ti ko awọn mẹta yooku yọ ninu igbekun awọn ọdaju ẹda naa.

Miliọnu mẹwaa Naira la gbọ pe awọn olubi eeyan ọhun gba ko too di pe wọn tu wọn silẹ ninu igbekun.

Ta o ba gbagbe, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, lawọn igiripa ọkunrin kan ti wọn mura bii ṣọja pẹlu ibọn lọwọ, ya wọ inu oko nla kan ti awọn agbẹ pọ si laarin ilu Iṣẹgun si Ipapo, ti wọn si ji mẹrin gbe ninu wọn.

Lọjọ keji ti iṣẹlẹ yii waye lawọn ọdaju eeyan yii yinbọn pa ọkan ninu awọn agbẹ mẹrin naa ki wọn too fowo gba awọn mẹta yooku silẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2022 yii, Oludasilẹ oko nla ti wọn ti ṣiṣẹ ibi naa, Ọgbẹni Rasheed Adepọju, fi ẹdun ọkan rẹ han pe awọn ọdaju agbebọnrin ọhun gbẹmi ọkan ninu awọn eeyan naa.

O ni, “Nigba ti a n kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi ẹni ti wọn pa, a dupẹ pe a tiẹ ri awọn mẹta yooku gba silẹ. Iṣẹlẹ yii ba mi ninu jẹ gan-an, a o maa ṣalaye nipa ẹ nigba ti asiko ba to”.

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Amofin Adebayo Lawal, naa fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin nigba to n kopa ninu ayajọ ọsẹ wọn ninu ọgba NUJ to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, lọjọ Aje ọsẹ yii.

O ni wahala kekere kọ ni ijọba Gomina Ṣeyi Makinde ṣe ko too di pe wọn gba awọn mẹtẹẹta silẹ pẹlu bo ṣe jẹ pe ọpọlọpọ ọjọ lajọ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ yii, lo ninu igbo lati mọ ibi ti awọn ajinigbe ko awọn eeyan naa pamọ si.

Leave a Reply