Faith Adebọla, Eko
Titi dasiko yii lawọn ẹlẹwọn atawọn oluṣọ wọn ṣi n sọrọ nipa ‘iṣẹ iyanu’ kan to tọwọ gbajugbaja adẹrin-in poṣonu onitiata ilẹ wa, James Ọlanrewaju, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ṣẹlẹ, lahaamọ ọgba ẹwọn Kirikiri to wa l’Ekoo, ọwọ lasan lọkunrin naa fi pa ejo nibi tawọn gende atawọn ẹlẹwọn to ṣan-an-gun ti n sa kijokijo kiri.
Ọkan ninu awọn ojiṣẹ Oluwa to maa n lọọ ṣewaasu fawọn ẹlẹwọn loorekoore nibẹ lo sọ nipa iṣẹlẹ naa f’ALAROYE.
O ni bi Baba Ijẹṣa ṣe fẹẹ lọọ gba itọju ni ileewosan tawọn ẹlẹwọn n lo laarin ọsẹ to kọja yii, bẹẹ lo kọsẹ ba awọn eeyan ti wọn n sa asala fẹmii wọn, ti onikaluku si n ṣe gidigidi, wọn ni ejo nla kan ni wọn ri nitosi ọfiisi ọga agba awọn ẹṣọ inu ọgba naa, ti wọn n pe ni Chief Warden, ejo naa ti sa sabẹ jẹnẹretọ kan. Bawọn eeyan ṣe ri ejo ti wọn lo tobi gidigidi yii lawọn kan lara wọn yọ igi, irin ati okuta, lati fi pa a, ṣugbọn ako-ta-giri ni t’ejo, pẹlu ibẹru ni kaluku wọn n tadi mẹyin, ko sẹni to fẹẹ sun mọ ọn.
Wọn ni bi Baba Ijẹṣa ṣe de’bẹ lo beere ohun to ṣẹlẹ ti gbogbo wọn fi n rọ girigiri, ni wọn ba ni ejo nla kan ni wọn n wọna lati pa. Taara ni wọn ni oṣere yii sidii jẹnẹretọ naa, o ti i ṣubu sẹgbẹẹ kan, ẹẹkan naa lo di ejo naa mu, o fi i lakalaka, lo ba la a mọlẹ pọọ, bẹẹ lejo ohun n ja rapa nilẹ, o si ku.
ALAROYE gbọ pe niṣe lariwo ta gee, ti ẹnu ya awọn to wa nibẹ fun igboya ati ijafafa ọkunrin yii, ati bo ṣe le di ejo nla mu bẹẹ, to si pa a lai lo ohun ija kankan, n lawọn eeyan ba n royin iṣẹlẹ ọhun fun ara wọn.
Tẹ o ba gbagbe, Baba Ijẹṣa dero ẹwọn lọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun yii, latari bile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko kan ṣe da a lẹbi ẹsun fifi ibalopọ lọ ọmọde, atawọn ẹsun mi-in to tan mọ ọn, ti wọn si sọ ọ sẹwọn ọdun mẹrindinlogun, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ti pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, o si ti beere fun beeli lẹwọn, ki igbẹjọ bẹrẹ lo n reti.