Faith Adebọla
Pampẹ ofin to ta ko ṣiṣẹ okoowo aibofinmu ati tita atare obitibiti owo silẹ okeere ti mu kọmiṣanna feto idajọ lasiko iṣejọba Gomina Babatunde Faṣọla nipinlẹ Eko, Amofin Agba Ọlaṣupọ Ṣaṣorẹ, dero kootu, ọkunrin naa si ti n kawọ pọnyin rojọ.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ajọ to n gbogun iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), wọ ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgọta naa lọ sile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Ikoyi, nipinlẹ Eko, lori ẹsun mẹrin ọtọọtọ.
Lara awọn ẹsun naa ni pe lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2014, afurasi ọdaran yii sanwo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un owo dọla Amẹrika fun Olufọlakẹmi Adelọrẹ, owo beba lo fi sanwo ọhun, dipo ti yoo fi lo banki, wọn ni Ọgbẹni Auwalu Habu kan lo fi i ran, Ọgbẹni Wale Abọdẹrin naa si mọ nipa ẹ.
Bakan naa ni wọn lo tun ko ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un owo dọla mi-in fun Ikechukwu Oguine, ọna aitọ lo si gba sanwo ọhun.
Wọn lawọn ẹsun yii ta ko abala ki-in-ni, ikẹrindinlogun, ikejidinlogun, ati ikejidinlọgọrin iwe ofin ti wọn fi de okoowo aitọ ati kikowo rẹpẹtẹ kiri.
Amọ, nigba ti Adajọ Chukwujekwu Aneke beere lọwọ olujẹjọ naa boya o jẹbi tabi ko jẹbi, o loun ko jẹbi.
Agbẹjọro EFCC, Ọgbẹni Bala Sanga, tọrọ pe ki wọn jẹ ki afurasi naa maa lọ si ahamọ awọn EFCC titi to fi maa pari igbẹjọ rẹ.
Ṣugbọn lọọya olujẹjọ, Amofin agba C. A. Candide-Johnson, to lewaju fawọn amofin agba mẹta mi-in, Muiz Banirẹ, Adeṣegun Adebọla, ati Chijoke Okoki, pe kile-ẹjọ ṣiju aanu wo onibaara awọn, ki wọn faaye beeli silẹ fun un lorukọ ara ẹ, tori eeyan to gbajumọ lawujọ ni.
Wọn ni ko sẹni to mu un ni tipa lati wa si kootu, wọn ni oun lo fẹsẹ ara ẹ rin wa, o si de lasiko, ati pe gbajumọ ni onibaara awọn, ki i ṣẹni to le sa lọ. Wọn tun ran adajọ leti pe ni gbogbo igba ti EFCC fi n ṣewadii, afurasi yii ko da wọn laamu, bi wọn ṣe n pe e lo n jẹ wọn, to si n dahun ibeere wọn, tori lati bii ọdun mẹta sẹyin ni iwadii ti bẹrẹ lori ẹsun naa kọrọ too di tile-ẹjọ bayii.
Agbẹjọro olupẹjọ naa loun ko ta ko fifun afurasi yii ni beeli, ṣugbọn toun ni pe igbakuugba ti wọn sun igbẹjọ si, o gbọdọ yọju, ko gbọdọ si awawi kan.
Adajọ ni nigba toun wo ọrọ ọhun sọtun-un sosi, ipinnu oun ni pe awọn yoo yọnda beeli fun afurasi yii lati maa tile waa jẹjọ, tori ofin sọ pe afurasi ṣi ni ọdaran kan titi digba ti ẹri ba fẹsẹ mulẹ pe ọdaran ni loootọ.
Latari eyi, wọn faaye beeli miliọnu lọna aadọta Naira ati oniduuro kan to ni iye owo yii kan naa lọwọ silẹ fun Ṣaṣọrẹ.
Ki i ṣe oniduuro lasan o, ẹni naa gbọdọ ti de ipo darẹkitọ ati Akọwe agba ti oyinbo n pe ni Permanent Secretary, o si gbọdọ ṣi wa lẹnu iṣẹ ọba.
Bi ko ba ri awọn nnkan wọnyi, wọn ni ko ṣi maa lọọ gbatẹgun alaafia lahaamọ EFCC na niyẹn.