Florence Babaṣọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti gbe Lukman Tijani Ọpẹyẹmi, ẹni ti ọwọ tẹ lori ẹsun pe o pa obinrin kan, ọmọ-ọmọ rẹ ati ọmọ-aburo rẹ niluu Iniṣa, lọ sile-ẹjọ.
Lukman, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ni wọn sọ pe o lọ si ile Arabinrin Sarah Oyediran laago mọkanla alẹ ọjọ kọkanlelogun, oṣu keje, ọdun yii, to si fi ọbẹ gun oun ati awọn ọmọ meji; Adeniran Toyin ati Onifade Favour pa
Agbefọba to gbe Lukman lọ sile-ẹjọ Majisreeti ilu Okuku, nijọba ibilẹ Okuku, ASP Mustapha Tajudeen, ṣalaye pe Lukman tun ji ATM ileefowopamọ Wema to jẹ ti Ọgbẹni Tunde Solomon Oyediran, to si gba ẹgbẹrun lọna ọọdunrun-un naira (#300,000.00) ninu ẹ ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.
Ẹsun meje ni agbefọba ka si Lukman lẹsẹ, lara wọn ni ẹsun idigunjale, ole-jija, ipaniyan, igbiyanju lati sa kuro lakolo ọlọpaa, biba awọn nnkan ọlọpaa jẹ.
O ni iwa to hu naa nijiya labẹ abala okoolelọọọdunrun-un o din ẹyọ kan (319) ati ọtalenirinwo o din mọkanla ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo.
Adajọ Majisreeti naa, O.B. Adediwura, paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Lukman sọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan-an, ti igbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.
Adediwura sọ pe ki agbefọba ṣe ẹda iwe ipẹjọ naa, ko si mu un lọ si ẹka DPP nileeṣẹ eto-idajọ ipinlẹ Ọṣun.