Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin oniṣowo koko kan, Lanre Adesida, ti pade iku ojiji lasiko to n ṣe ‘kinni’ lọwọ fun ale rẹ, Abilekọ Hadijat Oniyide, ninu otẹẹli kan kan ti wọn n pe ni Step-Down, niluu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa yii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Lanre, to dipo oṣelu mu n’Iwọ Oorun ijọba ibile Ondo, ti wọn lo tun dupo kansẹlọ ri la gbọ pe oun ati obinrin naa de si ile-itura yii ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ naa ko too di pe ọkunrin ẹni ọdun mejilelaaadọta ọhun bẹrẹ si i pọkaka iku nibi ti awọn mejeeji ti n ba ara wọn lo pọ lọwọ.
Hadijat kọkọ fẹẹ gbiyanju ati sa lọ loju-ẹsẹ to ṣakiyesi pe ere ifẹ ti awọn n ṣe ti fẹẹ gbọna mi-in yọ, ṣugbọn ọkan ninu awọn oṣiṣẹ-binrin ileetura naa, ẹni ti wọn porukọ rẹ ni Morayọ fura si i, lo ba da a duro ni tipatipa.
Kiakia ni wọn lo sare lọọ pe manija otẹẹli ọhun, ti gbogbo wọn si jọ da rẹirẹi lọ sinu yara ti awọn mejeeji ti n ṣe ‘kinni’ fun ara wọn. Iyalẹnu lo jẹ pe oku Lanre ni wọn ba nihooho ọmọluabi lori bẹẹdi.
Wọn ko fakoko ṣofo rara ti wọn fi fi iṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti. Lẹyin eyi ni wọn gbe oku ọkunrin oloṣelu naa lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa niluu Ondo.
Ninu ọrọ to ba akọroyin ALAROYE sọ, manija ile-itura ọhun ni gbọngan igbafẹ loun wa, nibi ti oun ti n da awọn onibaara kan lohun nigba ti Morayọ sare waa ba oun, to ni oun ri Hadijat to n pooyi, to si n jan ẹsẹ mọlẹ lẹyin to sa jade ninu yara ti wọn wọ si.
O ni loju-ẹsẹ loun ti ko awọn eeyan atawọn ẹsọ alaabo otẹẹli naa lọ sinu yara ti wọn gba, nibẹ lawọn si ti ba Lanre lori bẹẹdi to ti ku.
O ni alaye ti Hadijat ṣe fawọn ni pe ni kete ti awọn ba ara awọn sun tan ni Lanre sọ foun pe o n rẹ oun, bẹẹ ni oun ri i to n gbọn pipiipi, eyi lo ni o ṣokunfa bi oun ṣe sa jade pẹlu ibẹru, ki Morayọ too da oun duro.
Lẹyin eyi lo ni awọn fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti oun ati meji ninu awọn oṣiṣẹ awọn, Morayọ ati Mary, si tẹle Hadijat lọ si teṣan, nibi ti awọn ti ṣe akọsilẹ gbogbo ohun to ṣẹlẹ.
Ninu alaye ti ẹnikan to ba wa sọrọ, ṣugbọn to ni ka ma darukọ oun ṣe fun wa, o ni lati inu oṣu Kin-in-ni, ọdun ta a wa yii, lawọn ololufẹ mejeeji ti n gbe ara wọn wa si ile-itura naa lati ba ara wọn sun.
O ni Lanre ni iyawo to fẹ sile, to si bimọ fun un, bẹẹ ni Hadijat naa lawọn ọmọ tirẹ to bi, bo tilẹ jẹ pe ko si nile ọkọ.
Ibi kan nitosi otẹẹli naa lo ni Lanre maa n gbe ọkọ rẹ pamọ si nigbakuugba ti wọn ba ti jọ wa sibẹ. O fi kun un pe Hadijat ni yoo kọkọ bọ silẹ, ti yoo si wọle lọọ duro de ale rẹ ninu otẹẹli ọhun.
Ibi kan naa yii lo ni Lanre gbe ọkọ rẹ si lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, bo tilẹ jẹ pe ọtọọtọ lawọn mejeeji de si ile-itura naa. Awọn agbofinro la gbọ pe wọn waa pada gbe ọkọ naa lọ si agọ wọn.
Ọlọpaa kan to ba wa sọrọ labẹ aṣọ ni loootọ lawọn ti fi pampẹ ofin gbe Hadijat, ti awọn agbofinro si ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori ohun to le fa iku airotẹlẹ ti ọkunrin naa ku.
O ni awọn ko ni i pẹẹ fi afurasi ọhun ṣọwọ si ọfiisi awọn ọlọpaa to n ṣe iwadii ẹsun ọdaran l’Akurẹ.