Florence Babaṣọla, Oṣogbo
O kere tan, eeyan marun-un lo fara gbọta nibi ifẹhonu han to waye lẹyin tijọba ipinlẹ Ọṣun kede Ọmọọba Ọlalekan Akadiri gẹgẹ bii Akinrun ti ilu Ikirun tuntun.
Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, nijoba kede Akinrun tuntun naa, kia si ni awọn kan ti wọn ko fara mọ iyansipo Ọmọọba Akadiri bẹ soju titi, ti wọn si n fẹhonu han kaakiri.
Lasiko iféhonu han naa, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣe sọ, eeyan marun-un ni wọn fara gbọta.
Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe alaafia ti pada sinu ilu naa lẹyin ti igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa ṣaaju awọn agbofinro lọ sibẹ.
A oo ranti pe laipẹ ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, kede iyansipo awọn ọmọọba mẹwaa si ipo ọba, ninu eyi ti Akinrun ti ìlu Ikirun ati Onikoyi ti ilu Ikoyi wa.
Ojo kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, lawọn afọbajẹ mẹfa ninu awọn meje dibo yan an ninu ipade wọn, to si fi idi awọn oludije mẹtadinlogun to ku bẹlẹ.
Ọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun 2021, ni ori apeere Akinrun ṣofo, lẹyin ti Ọba Rauf Ọlawale Adedeji darapọ mọ awọn baba nla rẹ.
Awọn ọba yooku tijọba ipinlẹ Ọṣun tun yan ni Alabere ti Abere, Ọmọọba Adefẹmi Mutalib Adelakin, Ọmọọba Adekoyejọ Adebusoye Oyebamiji to jẹ Oluwoye ti Iwoye.
Ọmọọba Ademiju Kehinde Adifagbẹru di Arogbo ti Irogbo-Ijeṣa, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Atakumọsa, Ọmọọba Atoyebi Waheed Ọlalekan di Oniwọru ti Wọru.
Ọmọọba Taofeek Akande Morẹnigbade Iyiọla di Olukoyi ti Ikoyi, Ọmọọba Charles Adeṣina Ogunwusi di Atilade ti Faṣina, Ọmọọba Ọlaboye Mathew Ọlayẹmi di Olu ti Ẹyẹntanlẹ.
Ọmọọba Ọbafẹmi Anthony Adediran Obisanya di Asominasi ti Idominasi, Ọmọọba Oyedunmade Oluwabukọla Akọsìle di Alaje Ọlọpọn ti Ọlọpọn Ajegunlẹ ni Igangan, ti Ọmọọba Adefẹmi Mutalib Adelakin si di Alabere ti Abere.