Monisọla Saka
Ọdẹ aṣọle kan to n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ Corporate Victoria Gardens Security Company, Desmond Gudyu, ti lu ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Akeem Nuhu, pa, lasiko ti ede aiyede waye laarin wọn lori ọrọ owo ile, lagbegbe Lugard Avenue, Ikoyi, nipinlẹ Eko. Gudyu ti wọn gba lati maa ṣọ ile kan lagbegbe naa loun naa sọ ara ẹ di lanlọọdu ọsan gangan, ṣe aisi nile ologinni ni i sọ ile di ile ekute. Nigba ti ko ti si awọn to nile ni arọwọto, ọkunrin yii gba Nuhu sinu ile kotopo to wa lẹnu geeti ti wọn fi jin in pe ko maa gbe lẹyin ti wọn ti jọ sọrọ lori iye owo ti Nuhu yoo maa san fun un.
Nuhu ti n sanwo fun ile Gudyu gẹgẹ bii ajọsọ wọn ko too di irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ti Nuhu to n tẹle ọkọ kiri nileeṣẹ piọwọta kan lagbegbe naa, ko ri owo ti wọn ti jọ fẹnu ko le lori ọhun san. Ọrọ owo yii lo bi ede aiyede laarin wọn, ẹṣẹ kan ni Gudyu gbe fun Nuhu to fi mu idi lọọlẹ, to si ṣe bẹẹ dagbere faye.
Ọkunrin agbaṣẹṣe kan, Ayọ Ipadeọla, to n ṣiṣẹ lagbegbe naa ṣalaye pe, “Ọkunrin ọlọdẹ yẹn lo n gbe ninu ile ọhun, ileeṣẹ piọwọta ni Nuhu ti n ṣiṣẹ ni tiẹ. Airibi gbe lo mu koun ati Gudyu ṣe adehun pe ko maa waa sun nile megaadi to maa n wa lẹnu geeti toun naa n gbe, yoo si maa sanwo oorun to n sun nibẹ foun. To ba ti ji laaarọ kutukutu to gba ibi iṣẹ lọ, iyooku tun digba to ba dari de lalẹ. Ṣugbọn lalẹ ọjọ Mọnde tiṣẹlẹ yii waye, ọkunrin ọlọdẹ yẹn ni Nuhu ti jẹ oun lawọn owo ile kan, nibẹ naa ni wọn si ti bẹrẹ si i tahùn sira wọn. Ọrọ iyan jija yii lo mu ki Gudyu tawọ si Nuhu, bo ṣe rọra fọwọ ta a laya bayii ni Nuhu ṣubu lulẹ, ti ko si le dide mọ”.
A gbọ pe wọn sare gbe ọkunrin naa lọ sileewosan awọn ọlọpaa to wa lagbegbe Falọmọ, nibẹ lo si pada dakẹ si, wọn si ti gbe oku ẹ lọ sile igbokuu-pamọ-si ti ileewosan Federal Medical Centre, Ebute-Metta, fun ayẹwo iru iku to pa a.
Agbẹnusọ ọlọpaa Eko, Benjamin Hundenyin, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni afurasi naa ti wa lahaamọ awọn agbofinro, wọn si ti n fọrọ wa a lẹnu wo.