Ọlọpaa ti mu awọn oṣiṣẹ ile Davido mẹsan-an lori iku ọmọ rẹ

Monisola Saka

Mẹsan-an ninu awọn oṣiṣẹ ti wọn wa ninu ile ọkunrin olorin ilẹ wa nni, David Adeleke, ni awọn olọpaa ti ko fun iforọwanilẹnuwo lori iku to pa Ifeanyi, ti wọn fi sakata wọn, to si ku sinu omi iwẹ lasiko ti awọn obi rẹ ko si nile. Wọn ni ki wọn waa ṣalaye ohun ti wọn mọ nipa iku ọdọmọde naa ati ibi ti wọn wa lasiko iṣẹlẹ ọhun.

Lara awọn ti wọn ti wa lagọọ ọlọpaa ni nani ti wọn gba lati maa tọju ọmo yii ati alase to maa n se ounjẹ fun wọn ninu ile atawọn mi-in. A gbọ pe lara ẹsun ti awọn ọlọpaa tori rẹ mu wọn ni iwa aika nnkan si, eyi to jẹ ki ọmọ ti wọn fi si ikawọ wọn lọọ luwẹẹ ninu omi, ti ẹnikẹni ninu wọn ko si ri i titi ti ọmọ naa fi ku sinu odo ọhun.

Wọn ni ohun to si n jẹ iyalẹnu ni bi ọmọ ọdun mẹta yii ṣe ṣi ilẹkun onirin nla to wa ninu ile naa funra rẹ, to si fi jade lọ sinu odo iluwẹẹ yii, ti ko si si ẹni to mọ.

A gbọ pe pe awọn obi ọmọ yii, Davido ati Chioma ko si nile lasiko ti iṣẹlẹ aburu naa ṣẹlẹ. Inu odo iluwẹẹ atọwọda to wa ninu ile naa la gbọ pe ọmọ yii ko si, ti ko si sẹni to ri i titi to fi mumi yo, nigba ti wọn yoo si fi gbe e jade, ọmọ naa ti jade laye.

Bo tilẹ jẹ pe wọn pada gbe e lọ sọsibitu lati du ẹmi rẹ, awọn dokita ni o ti jade laye.

Leave a Reply