Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti ba David Adeleke, ti gbogbo eeyan mọ si Davido, kẹdun iku ọmọ rẹ ọkunrin, Ifeanyi, o ni ajalu nla ti ẹnikẹni ko le gbadura rẹ ni.
Bakan naa ni Oyetọla ba Baba Davido, Dokita Deji Adeleke, ṣọfọ lori iku ọmọ-ọmọ rẹ, o ni oun ni imọlara irora naa.
Gomina gbadura pe ki Ọlọrun tu gbogbo idile naa ninu lasiko ilakọja nla yii.
Ninu atẹjade ti Akọwe iroyin gomina, Ismail Omipidan, fi sita ni Oyetọla ti sọ pe, “Lorukọ mi ati awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun, mo kẹdun pẹlu Davido lori iku ọmọ rẹ, Ifeanyi.
“Mo mọ bo ṣe lagbara to lati padanu ọmọkunrin ti gbogbo wa ri to n ṣere kaakiri lọsẹ to kọja. Mo gbadura pe ki Ọlọrun tu iwọ ati Chioma ninu.
“Mọ daju pe Ọlọrun yoo bukun ẹyin mejeeji pẹlu ọmọkunrin miiran ti yoo ba yin kalẹ laipẹ.
“Mo gbadura pe ki Ọlọrun fun awọn obi ẹyin mejeeji ni ọkan lati gba adanu nla yii.”