Gbenga Amos, Ogun
Adura gidi lorin gbajugbaja olorin Juju nni, Ebenezer Obey, to kọrin pe “ohun ta o jẹ la n wa lọ Baba, ka ma pade ohun ti yoo jẹ wa” o. Iyaale ile kan, Abilekọ Tawakalitu Abdulazeez, tawọn eeyan mọ si Alaaja, ti kagbako iku ojiji, ata ti kọsitọma ẹ fẹẹ fi sebẹ lo n lọ lọwọ, idi ẹrọ ilọta naa lo wa ti ọkọ tipa kan fi ya bara kuro lori titi lojiji, to si pa a lẹsẹkẹsẹ.
Iṣẹlẹ yii waye ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ ki-in-ni, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni ibudokọ Oluwo-Geeti, nidojukọ Ojodu Carwash, lagbegbe Oke-Aro, lẹnu aala ipinlẹ Ogun ati Eko.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ sọ f’Alaroye pe ere buruku ni tipa naa n sa bọ, to fi ya pa ẹni ẹlẹni yii, wọn l’Ọlọrun lo ko Priscilia, ọmọbinrin to waa lọ’ta naa yọ, afi bii ẹni pe o ti mọ pe ewu nla kan fẹẹ ṣẹlẹ, tori gẹrẹ to gbe ata naa silẹ pe ki Alaaja ba oun lọ ọ, oun fẹẹ sure mu nnkan ninu ṣọọbu mama oun to wa nitosi, niṣẹlẹ aburu naa waye.
A gbọ pe kete ti jamba yii ṣẹlẹ ni dẹrẹba ọkọ naa ati awọn ọmọọṣẹ meji ti fo bọ silẹ ninu ọkọ naa, k’awọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti juba ehoro, wọn sa lọ rau. Awọn aladuugbo ni wọn waa fa oku mama agbalagba naa yọ labẹ tipa ọhun, ti kaluku wọn si n ṣedaro iku gbigbona to ku.
Ko pẹ lẹyin eyi lawọn ọlọpaa de lati ẹka ileeṣẹ wọn to wa l’Agbado, nipinlẹ Ogun. Wọn lawọn ọlọpaa naa fẹẹ wọ mọto fa jamba yii lọọ teṣan wọn, ṣugbọn awọn bọisi adugbo naa yari mọ wọn lọwọ, wọn o si gba pe ki wọn gbe mọto ọhun kuro nibi iṣẹlẹ yii, wọn lọgbọn ati doju ẹjọ ru lawọn ọlọpaa fẹẹ da, bo tilẹ jẹ pe eyi fa awuyewuye gidi.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, loun o ti i gbọ nipa ọrọ yii nigba ta a kan si i lori aago.
A gbọ pe wọn ti gbe oku Tawakalitu lọọ ileewosan, wọn si ti tu’fọ iṣẹlẹ yii fawọn mọlẹbi atọmọ rẹ.