Jọkẹ Amọri
Inu ibinu ati irunu gidi ni Alaaji Kazim Adeoti Adesọji, ọkunrin kan to maa n gbe fiimu awọn oṣere jade, to si tun n ta awọn kasẹẹti oṣere, to tun waa jẹ ọkọ fun gbajumọ oṣere ilẹ wa, Mercy Aigbe, wa bayii. Ko si pa ibinu naa mọra rara. Eyi ko sẹyin bi aWọn kan ṣe lo fọto rẹ si iroyin ọmọ jayejaye Eko kan ti wọn ni ileeṣẹ to n gbogun ti lilo ati tita oogun oloro nilẹ wa, NDLEA n wa.
Ṣe bi wọn ba n sọ pe ‘gbe e gbe e gbe e, teeyan ko ba tete ba wọn gbe e, afaimọ ki wọn ma gbe e sọ si ẹyinkule oluwarẹ. Eyi lo difa fun ọkunrin to ni Ibakatv to wa lori ayelujara ọhun, to fi pariwo sita pe oun kọ ni ọmọ jayejaye Eko tawọn NDLEA n wa niitori to gbe oogun oloro.
Ninu atẹjade kan ti ọkunrin to fẹ arẹwa oṣere nni, Mercy Aigbe, fi sori Instagraamu rẹ lo ti sọ pe ‘Awon eeyan ti pe akiyesi mi si ọrọ kan to n lọ nigboro, ninu eyi ti awọn kan ti kọ ọ sibẹ pe ‘NDLEA n wa Adekaz lori oogun oloro.’
‘Ẹ jẹ ki n fi asiko yii sọ ootọ to wa nidii ọrọ ti wọn n gbe kiri yii, mo fẹẹ ṣe eleyii nitori awọn ọrẹ mi, awọn alabaaṣiṣẹpọ mi, ati gbogbo araalu lapapọ ti wọn ti n kan si emi ati awọn mọlẹbi mi nitori ọrọ yii.
‘Lakọọkọ na, Họnọrebu Kazim Adesọji Adeoti lorukọ mi, emi ni Alaga Ibakatv ati Alaṣẹ Adekaz Production, emi ki i ṣe Alaaji Ademọla Afọlabi Kazeem, ẹni ti ileeṣẹ to n gbogun ti lilo ati tita oogun oloro, (NDLEA) n wa kiri.
Mo jẹ ilu mọ-ọn-ka to n gbe fiimu jade, mo tun n ta fiimu, bẹẹ ni mo si tun n ṣowo ka ba ni ra ile ati ilẹ. Mi o ba wọn lọwọ si awọn owo ti ko bofin mu ri, ootọ ti mo n sọ yii, awọn ọrẹ mi atawọn ẹlẹgbẹ mi l’Amẹrika le jẹrii si i.
‘O jẹ ohun to ya mi lẹnu, bẹẹ ni mo si n fura pe ejo ọrọ naa lọwọ ninu lori bi awọn iweeroyin kan ṣe n gbe iroyin naa pẹlu fọto mi.
‘O yẹ ki iru awọn ileeṣẹ iweeroyin to n gbe orukọ orukọ mi yii ṣe iwadii wọn daadaa, ki wọn si beere fọto to yẹ ki wọn lo pẹlu iroyin wọn, dipo ti wọn fi n ba orukọ mi ati ti idile mi jẹ pelu bi wọn ṣe n lo fọto mi lọna ti ko tọ. Mi o mọ ibi ti iwadii ijinlẹ lori iroyin lọ lorileede yii lasiko yii.
‘Ni itẹnumọ, mi o ki i ṣe ẹni kan naa tabi lọnakọna tan mọ Alaaji Ademọla, ọkunrin olotẹẹli , to si tun jẹ ọmọ jayejaye ti wọn sọ pe wọn n wa lori ọrọ oogun oloro.
‘Mo rọ awọn mọlẹbi mi, awọn ọrẹ, alabaaṣiṣẹpọ, awọn ti okoowo jọ pa wa pọ ati gbogbo araalu ki wọn ma gba ọrọ yii gbọ, ki wọn si ma ki orukọ mi mọ ọkunrin ọmọ jayjaye tawọn NDLEA n wa.
‘Lakootan, emi ati mọlẹbi mi n reti ki awọn iweeroyin ati awọn akọroyin ori ayelujara tabi ẹnikẹni toti ṣeeṣẹ lo fọto mi pẹlu iroyin ti ki i ṣe ootọ yii tọrọ aforiji kiakia.
Bi wọn ba kọ lati ṣe bẹẹ laarin wakati mejidinlaaadọta, mo maa gbe wọn lọ sile-ẹjọ.
Bẹẹ ni ọkọ Mercy kọ ọrọ naa si ori Instagraamu rẹ lati wẹ ara rẹ mọ kuro ninu ọrọ ti ko kan an ti wọn n gbe kiri.