Pẹlu bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe lọtun-un losi, ti wọn si n paayan kaakiri, Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, ti sọ pe ki awọn araalu ma da awọn to n sọ pe eto aabo ilẹ wa n buru si i lohun o. Buhari ni ohun ti awọn orileede ilẹ okeere n sọ nipa eto aabo ile wa ki i ṣe ootọ rara. O ni awọn ipenija to n waye lawọn ipinle kaakiri orileede yii jẹ eyi ti ijọba le kapa rẹ.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Aarẹ gba ẹnu Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina sọrọ naa lasiko ti wọn n ṣide ipade kan, eyi to wa fun awọn to n mojuto ẹka iroyin lawọn ileeṣẹ aabo ara ẹni laabo ilu ti wọn n pe ni Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCD), eyi to waye niluu Abuja.
Adeṣina ni eto aabo ilẹ wa ti daa de aaye ibi kan. O ni bo ti tilẹ jẹ pe ko ti i lọ tan patapata, sibẹ, ki i ṣe pe o n le si i.
Oludamọran Aarẹ yii ni ohun yoowu ki awọn orileede agbaye maa sọ lori ọrọ aabo ilẹ wa ki i ṣẹ ootọ.
Adṣina ni, ‘Awọn ẹṣọ alaabo ilẹ wa kapa eto aabo ilẹ wa, bẹe ni wọn si n mojuto o bo ṣe yẹ, n ko fara mọ ọrọ ti wọn n sọ kiri pe eto aabo ilẹ wa n le si i. Ko le si i rara, o wa ni ikapa wa, a si n ṣe amojuto re, a oo si maa mojuto o titi ti ohun gbogbo yoo fi lọ silẹ patapata.
Bakan naa ni Ọga agba awọn sifu difẹnsi, Ahmed Audi, sọ pe gbogbo agbara ni ijọba n sa lati ri i pe ipenija eto aabo di afisẹyin ti eegun n fi aṣọ. O waa gba awọn ọmọ orileede yii niyanju lati ma ṣe tẹti si ọrọ ti awọn kan n sọ kiri pe eto aabo ilẹ wa ko daa. O ni iṣẹ eto aabo wa lọwọ ijọba ati awọn araalu.
O waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ pe ki wọn ronu ọgbọn ati ọna oriṣiiriṣii lati ṣamulo ki ohun gbogbo le lọ bo ṣe yẹ lasiko eto idibo to n bọ yii ti iṣẹ yoo wa fun wọn lati ṣe.