Monisọla Saka
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje, rọ awọn Hausa-Fulani ti wọn fi ipinlẹ Eko ṣebugbe lati fibo wọn gbe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ, Sẹnetọ Kashim Shettima, wọle ibo aarẹ to n bọ lọna yii labẹ asia ẹgbẹ APC.
Ganduje sọrọ naa lasiko ti oun, Kashim Shettima ati Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko ṣabẹwo saduugbo awọn Hausa to wa ni Alaba Rago, nijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko.
O ni, “Iroyin ayọ la mu wa fun yin lonii, to ba jẹ ti apa Ariwa ilẹ yii ni, ọrọ Tinubu gẹgẹ bii aarẹ wa lọdun to n bọ ti di ṣiṣe. A wa n reti ẹyin olugbe Eko naa lati waa ṣatilẹyin fun wa pẹlu ibo yin.
Nipinlẹ Kano, ohun to daju ni pe ibo ti Aṣiwaju maa ri nibẹ maa ju tawọn ipinlẹ yooku lọ. A waa n sọ eleyii bii ipenija fẹyin olugbe Eko naa lati ṣeleri fun wa pe ẹ maa fẹyin Kano janlẹ lati le gbe Tinubu depo”.
Shettima ni tiẹ sọ pe ibo ọdun 2023 yii lo maa da bii ẹsan oore fun Tinubu lati apa Ariwa, nitori pe latọjọ to ti pẹ loun naa ti n ṣatilẹyin fawọn oludije dupo lati apa Oke-Ọya fawọn ibo ti wọn ti di sẹyin.
“Mo fẹẹ mu ori yin ya lori pataki ibo ọdun to n bọ. Fun awa ta a wa lati apa Ariwa, asiko lati dupẹ oore niyi, tori lawọn ibo ta a ti di sẹyin, Aṣiwaju Bọla Tinubu ṣatilẹyin fawọn oludije dupo aarẹ nilẹ yii.
Lasiko ibo abẹle ọdun 2014 ati 2015 atawọn ibo gbogbogboo to tẹle e, ti ko ba si ti ibo ti wọn ri lawọn apa Guusu Iwọ Oorun orilẹ-ede yii ti Tinubu ṣe aayan rẹ ni, Aarẹ Buhari o ba ma depo Aarẹ to wa yẹn. Bẹẹ naa lọrọ ri lọdun 2019, asiko ti waa to lati san ẹsan oore bayii o. Eeyan iyi ni wa, o yẹ ka ṣiika adehun, idi niyi ta a fi fẹ kẹ ẹ dibo fun APC. Ni ti ibo gomina naa si ree, Babajide Sanwo-Olu ni mo fẹ kẹ ẹ tu yaaya, tu yaaya jade waa dibo fun”.
Ninu ọrọ tiẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu sọ pe, “Ẹ ti r’awọn iṣẹ akanṣe loriṣiiriṣii ta a n ṣe lagbegbe Iba atawọn nnkan meremere mi-in ta a n ṣe lagbegbe yii. Laipẹ yii la maa pari opopona marosẹ Eko si Badagry. Eyi to lọ si agbegbe Okokomaiko la maa fi kasẹ ẹ nilẹ nipari ọdun yii. Ọsibitu nla ta a n kọ si Iba naa o ni i pẹẹ pari, lati ibẹ la ti maa re si oju ọna lati Afromedia lọ si Kemberi, nitori ẹ la ṣe n bẹ yin lati dibo fun wa ka le pari awọn iṣẹ daadaa tijọba yii dawọ le”.
Nigba to n fesi si gbogbo ohun ti wọn ti sọ kalẹ, Alaga awọn eeyan apa Ariwa l’Ekoo, Alaaji Yusuf Badaru, ṣalaye pe awọn ẹya Hausa Eko o figba kankan pada lẹyin ẹgbẹ APC, o lawọn yoo tubọ ṣapa lati ri i daju pe ọkọọkan awọn ondupo naa lawọn gbe dori oye.