Ile-ẹjọ fontẹ lu oludije funpo gomina Rivers

 Ile-ẹjọ giga kan to jokoo ni ilu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers, ti fọwọ osi da ẹjọ ti wọn pe oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa, Siminalaye Fubara, pe ko lẹtọọ lati dije dupo gomina  ninu ibo ọdun to n bọ nu. Adajọ ni ẹjọ ti wọn pe yii ko lẹsẹ nilẹ. Ọkunrin yii ni Gomina ipinlẹ naa, Nyesome Wike n ṣatilẹyin fun lati gba ipo lọwọ re ti saa ọdun mẹjọ rẹ ba pari lọdun to n bọ.

Ọkan ninu awọn oludije funpo gomina ọhun, Oloye Morgan West, lo pe ọkunrin naa lẹjọ. Lara awọn ẹsun to fi kan an ni pe ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, bẹẹ ni ko si ni kaadi idanimọ ẹgbẹ naa lọwọ.

 Ṣugbọn niṣe ni Onidaajọ Adamu  T. Muhammed da ẹjọ naa nu bii omi iṣanwọ, o ni ko lẹsẹ nilẹ, bẹẹ ni ki i ṣe ibi to yẹ ko gbe ẹjọ naa wa lo gbe e wa.

Ko sẹni to ti i le sọ boya ọkunrin yii yoo gba ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lọ.

Leave a Reply