Sanwo-Olu ṣekilọ: Agbofinro to ba halẹ mọ araalu yoo ri pipọn oju ijọba mi

Faith Adebọla, Eko

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti ṣekilọ to nipọn fawọn agbofinro to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba ipinlẹ rẹ pe ki wọn lọọ ṣọra wọn gidigidi, o loun ko fẹẹ gbọ pe agbofinro kan n dunkooko mọ araalu lọnakọna. Ọkunrin yii lẹnikẹni to ba wọṣọ ọba, to si n lọwọ ninu iwa aitọ bẹẹ maa kan dudu inu ẹkọ lọdọ ijọba oun ni.

Sanwo-Olu sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla ọdun yii, lasiko ayẹyẹ ipari idanilẹkọọ akanṣe ọlọdọọdun kan ti wọn ṣe fawọn agbofinro ni Lagos State Public Service Development Centre, to wa ni Magodo, l’Ekoo.

Igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Dokita Ọbafẹmi Hamzat, to gbẹnu sọ fun ọga rẹ nibi ayẹyẹ naa sọ pe:

“Ijọba yii ko jawọ ninu ilakaka rẹ lati rọ timọtimọ mọ ilana ofin ati ẹtọ, ilana naa la si fi n ṣejọba wa. Tori ẹ, a o ni i fojuure wo agbofinro eyikeyii to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko to ba n halẹ mọ araalu, ti wọn n jaye ta-ni-maa-mu-mi, ti wọn n gba owo ẹyin, tabi ti wọn n lu araalu ni jibiti lọnakọna. Idi ta a fi n ṣeto idalẹkọọ wọnyi fun yin niyẹn.

“A oo tubọ maa ro awọn agbofinro wa lagbara pẹlu awọn nnkan eelo ati irinṣẹ igbalode to maa jẹ ki muṣemuṣe wọn tubọ da muṣemuṣe lẹnu iṣẹ ọba. Bẹẹ la o ni i fi ọrọ igbokegbodo wọn pamọ, gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe gbọdọ han faye ri ni, wọn si gbọdọ jihin faraalu.

“Ẹgbẹrun mẹjọ, ọọdunrun o le mẹrindinlogun, lẹyin agbofinro tẹ ẹ pari idalẹkọọ yin bayii, titi kan awọn ti wọn wa lati ajọ to n ri si lilọ-bibọ ọkọ loju popo, iyẹn Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), ajọ to n yẹ bi ọkọ ṣe dangajia si wo, iyẹn Vehicle Inspection Service (VIS), ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ, Kick Against Indiscipline (KAI) ati ajọ alaabo adugbo l’Ekoo, Lagos Neighborhood Safety Corp, LNSC.”

Ọga agba ile-ẹkọ ti wọn ti da wọn lẹkọọ naa, Abilekọ Abiọla Adeyinka, ni oṣu mẹta gbako lawọn fi n da awọn oṣiṣẹ wọnyi lẹkọọ, lara ẹkọ ti wọn si ri gba da lori ilana iṣẹ wọn, biba araalu lo tọwọtọwọ, bi wọn ṣe gbọdọ ni amumọra si, bi wọn ṣe ni lati maa bọwọ fun tọkunrin tobinrin, atawọn ọmọde si, didahun pada nigba ti pajawiri ba ṣẹlẹ, ati ajọṣe kaluku ajọ kan pẹlu omi-in.

O lawọn tun kọ wọn lori bi wọn ṣe gbọdọ maa ta kebekebe lẹnu iṣe si, ki wọn si jẹ ki laakaye wọn, wiwa lojufo wọn gbeṣẹ nigba gbogbo, tori toju-tiyẹ l’aparo fi i riran.

Leave a Reply