Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti ṣe ifilọlẹ akanṣe eto kan, eyi ti wọn porukọ rẹ ni Gba’le gba’ko lọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla yii.
Ilu Ọwẹna, eyi to wa ni aala ipinlẹ Ondo ati Ọṣun, nijọba Ifẹdọrẹ, ni wọn ti kọkọ ṣe ifilọlẹ eto ọhun, ki wọn too lọọ pari rẹ siluu Akurẹ, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ondo, nirọlẹ ọjọ naa.
Nigba to n sọrọ nibi eto naa, adari ẹṣọ Amọtẹkun ti ipinlẹ Ondo, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ sọ lasiko ninu ifilọlẹ eto naa pe gba’le gba’ko lawọn ti n peṣe aabo to peye fawọn araalu ati arinrin-ajo ni gbogbo igba ti ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun ba ti n sun mọle.
Alaga awọn adari ẹsọ Amọtẹkun lẹkun Guusu Iwọ-Oorun ọhun ni eeyan to le lọọọdunrun lawọn doola ẹmi wọn lọwọ awọn ajinigbe laarin asiko ti awọn fi ṣeto naa lọdun to kọja, ti awọn si tun ri ọkọ bii ọgọrin gba pada lọwọ awọn ole alọ-kolohun-kigbe.
O ni ọdun to kọja kan naa ni ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ati Ọṣun jọ bẹrẹ ka lọ-ka bọ lawọn ẹnubode ipinlẹ mejeeji, eyi to yọri si bọwọ ṣe tẹ ọpọlọpọ awọn ajinigbe, adigunjale atawọn ọdaran mi-in.
O ni gbogbo awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun to wa ni gbogbo ilẹ Yoruba lawọn jọ maa n ṣiṣẹ pọ lati ri i daju pe awọn ọdaran ko rọwọ mu rara lẹkun Guusu Iwọ-Oorun Naijiria.
Akọgun Adelẹyẹ ni ko si ani-ani pe oriṣiiriṣii awọn alejo ni wọn maa n ya wọlu lasiko ọdun, ti ọpọ si n lo anfaani ayẹyẹ ọhun lati huwa ọdaran.
O ni ohun to jẹ awọn logun ni bi aabo yoo ṣe wa fun awakọ, arinrin-ajo atawọn alejo to ba fẹ waa sọdun nibikibi nipinlẹ Ondo ati Ọṣun, lasiko ọdun to n bọ lọna.
O ni ẹnu wo lawọn agbaagba Yoruba fẹẹ maa fi sọ itan fawọn ọmọ wa lẹyin ọla pe awọn tun n san isakọlẹ fawọn ajoji lasan nilẹ baba wọn.
Olubadamọran lori ọrọ aabo fun gomina ọhun waa bẹbẹ fun atilẹyin awọn araalu ni gbogbo asiko ti eto naa ba fi waye nitori eti ọba nile eti ọba loko, eeyan ni n jẹ bẹẹ.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ Gomina Rotimi Akeredolu fun atilẹyin rẹ lati igba ti wọn wọn ti ṣe agbekalẹ ẹsọ Amọtẹkun, o ni ipinnu ati akitiyan Arakunrin lo fun awọn olugbe ipinlẹ Ondo lanfaani lati sun oorun asunwọra, eyi ti ko ri bẹẹ lawọn ipinlẹ mi-in.