Wọn ti mu Haruna o, baba afọju toun atọmọ rẹ n gbe oogun oloro

Jọkẹ Amọri

 Ṣe ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan bayii ni ti olohun, bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri fun awọn ọkunrin oniṣowo egboogi oloro meji kan ti ileeṣẹ to n gbogun ti tita ati lilo oogun oloro nilẹ wa, NDLEA, ti n wa lati ọjọ yii, ti wọn mu ṣikun laipẹ yii.

Agbẹnusọ ileeẹẹ naa, Femi Babafẹmi, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii. O ni ọkan ninu awọn meji yii, Nnebo Christopher, ni wọn ti n wa lori gbigbe oogun kan ti wọn n pe ni Co-codamol ogoji katọọnu, ti piisi oogun naa jẹ ọta le lọọọdunrun, o din mẹrin (360,800). Oogun yii ni wọn lo jẹ adapọ Panadol ati Codeine, to fẹẹ gbe sọda si oke okun ki wọn too ri ẹru naa ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed, to wa ni Ikẹja, ninu oṣu Kẹta ọdun yii.

Ọjọ kẹta, oṣu Kọkanla yii ni wọn too gba a mu.

Bakan naa ni ọwọ wọn tun tẹ ọmọ orileede Niger kan to jẹ afọju ati ọmọ rẹ, Burkar Aruna, ẹni ọdun mejilelaaadọta, ati ọmọ rẹ, Saka Haruna, ẹni ogun ọdun lori gbigbe oogun oloro yii kan naa. Lasiko ti awọn oṣiṣẹ NDLEA to wa loju ọna da wọn duro ni agbegbe kan ti wọn n pe ni Malumfashi, ni oju ọna Zaria, nipinlẹ Katsina, ni wọn ti mu wọn.

Nigba ti awọn eeyan naa n lọ si orileede Niger ni wọn ba igbo to to kilogiraamu to le ni ogun (20.5kg) ati giraamu marun-un  (5kg) oogun kan ti wọn n pe ni Exol-5 lọwọ wọn.

 

Leave a Reply