Adewumi Adegoke
Ẹgbẹ awọn Onigbagbọ nilẹ Naijiria, iyẹn Christian Association of Nigeria (CAN) ti yọ ara wọn kuro ninu awọn ẹgbẹ kan ti wọn ni wọn ko sẹni to mọ wọn, ti wọn ki i si i ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn ti wọn n sọ pe awon ti ṣatilẹyin fun Tinubu lati di aarẹ Naijiria. Ẹgbẹ Onigbagbọ yii ni awọn ko le maa takoto ọrọ pẹlu awọn ẹgbẹ ti ko le foju ara wọn han saye ti wọn n sọ bẹẹ, nitori ohun ti kaluku yoo jẹ lo n wa.
Luminous Jannamike to jẹ Oludamọran pataki lori eto iroyin fun aarẹ awọn CAN, Rev. Daniel Okoh, sọ pe ko sẹni to mọ awọn ti wọn n sọ pe awọn n ṣe atilẹyin fawọn kan yii, o ni ko sohun to jọ atilẹyin naa rara pẹlu lọdọ ẹgbẹ awọn Onigbagbọ.
O ni niwọn igba ti awọn ko ti le di ẹnikẹni, tabi awọn kan ti wọn pera wọn ni ‘iranṣẹ Ọlọrun’ lọwọ lati ṣe ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe, sibẹ, o ni awọn ko le maa takoto ọrọ pẹlu awọn eeyan naa ti wọn ni ẹgbẹ Onigbagbọ lawọn, ṣugbọn ti wọn ki i ṣe ara CAN
Ọkunrin naa ni ọrọ ati ipinnu awọn lori eleyii ko ruju, ipinnu awọn naa si ni pe awọn ko fara mọ ki ẹlẹsin kan naa jẹ aarẹ ati igbakeji. O ni ‘‘Ohun ti awa mọ ni pe ko sẹni to mọ awọn ti wọn n sọ yii, wọn ko si si ni abẹ isakoso CAN, niori eyi, awa ko ni ẹjọ kankan lati ba wọn ro. A o gbọdọ gbagbe pe onikaluku lo ni anfaani si ẹgbẹ to ba fẹ, ko si ṣe ohun to ba fẹ. Awọn eeyan yii ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ CAN. Awọn pasitọ ilu Abuja kan ni wọn kora wọn jọ, ti wọn si pinnu lati ṣe atilẹyin fun Tinubu, wọn o ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wa’’.
Lọjo Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni awọn pasitọ ilu Abuja kan ko ara wọn jọ, ti wọn si fohun ṣọkan pe awọn ṣe atilẹyin fun Tinubu ati Shettima lati di aarẹ ati igbakeji, wọn ni oun gan-an lo ni ohun to pe fun lati ṣe bẹẹ.
Ẹgbẹ naa ti wọn pe ara wọn ni Nigerian Coalition of Pastors for Good Leadership, ni wọn ko ara wọn jọ si gbọngan kan, nibi ti awọn alatilẹyin Tinubu ti wọn n pe ni City Boy Movement wa.
Ninu ọrọ ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Babatunde Oguntimẹhin ati Akọwe wọn, Fraiday Obi, sọ pe ko ni i da ko jẹ pe nitori pe ẹgbẹ APC fa aarẹ ati igbakeji to jẹ Musulumi kalẹ lawọn ṣe maa diju si amuyẹ to daa ti ẹgbẹ naa ni.
O ni loootọ lawọn fọwọ si i pe ko jẹ pe apa iha Guusu ni aarẹ yoo ti wa, nitori nigba ti saa ijọba yii ba tẹnu bepo, ara Oke-Ọya ni ẹni to wa nibẹ bayii, yoo si ti pari ọdun mẹjọ rẹ. Ni ilana pin-in-re la-a-re, ko tun ni i daa ko jẹ pe ẹni to wa lati agbegbe yii ni yoo tun waa pada sibẹ. A ni anfaani lati yan laarin Aṣiwaju Tinubu ati Peter Obi tawọn mejeeji wa lati apa Guusu, ṣugbọn ni tiwa, Tinubu lawa n ṣe atilẹyin fun.
O ni orileede yii nilo ẹni to ni imọ, to gbọn ṣaṣa, to si ni akikanju lati di aarẹ wa. Bakan naa lo ni awon akitiyan Tinubu loriṣiiriṣii lori ijọba awa-ara-wa ati ifẹ to ni si iṣọkan Naijiria lo jẹ ki awọn feẹ gbaruku ti i.