Jọkẹ Amọri
Inu idunnu nla ni ọga awọn onimọto nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluọmọ wa bayii o. Eyi ko sẹyin bi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ tun ṣe kẹkọọ gboye ẹkọ nipa Imọ Agbaye, ti wọn n pe ni International Relations nileewe giga fasiti ESGT University Dream Campus, Benin Republic, ni orileede Benin.
Lori Instgraamu rẹ lo gbe aworan ọmọ rẹ to kẹkọọ gboye naa si lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, to si ki i ku oriire, bẹẹ lo ni iwuri nla ni ọmọ naa jẹ fun oun pẹlu aṣeyọri to ṣe yii.
O kọ ọrọ iwuri nipa ọmọ rẹ naa pe ‘‘Si ọmọ mi daadaa, Idowu Akinsanya, King_west, mo ki ọ ku oriire aṣeyọri ti o ṣe yii, bi o ṣe kẹkọọ gboye nipa Imọ Agbaye ti wọn n pe ni International Relation ni ESGT University Dream Campus, Benin Republic.
‘‘Iwuri nla lo jẹ fun mi, ere gbogbo ilakaka rẹ lo han fun gbogbo aye lati ri bayii. Iwuri ni igbesi aye rẹ jẹ fun gbogbo awọn to yii ọ ka, to fi mọ awa obi rẹ paapaa. Nnkan kekere kọ ni ọrọ ẹkọ rẹ na wa, ṣugbọn eyi to dun mọ wa ninu ju ni bi a ṣe ri ọ pe o gun pepele aṣeyọri’’.
Latigba ti MC ti gbe ọrọ nipa ọmọ rẹ yii sori ikanni rẹ ni awọn ololufẹ rẹ ti n ki i ku oriire, ti wọn si n gbadura fun ọmọ naa pẹlu.
Ọpọ awọn ọmọ ọga awọn onimọto yii ni wọn n kawe lawọn ilẹ okeere kaakiri bii Amẹrika, Canada, London atawọn orileede mi-in.