Gbenga Amos, Ogun
Ko din ni eeyan mẹrin to ṣofo ẹmi lairoti nipinlẹ Ogun laarin Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kọkanla yii, si ọjọ keji, ọjọ Ẹti, Furaidee, latari ọṣẹ buruku awọn ajinigbe atawọn araalu to n bara wọn ja lagbegbe Ijẹbu.
Owurọ ọjọ Tọsidee ọhun, ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ lawọn afurasi ajinigbe ti wọn lugọ sinu igbo to wa laarin meji Oke Iṣaga ati Ilewo Orile, nijọba ibilẹ Ariwa Abeokuta fibọn mu olori ẹṣọ alaabo Fijilante agbegbe naa, Muhammed Ọkẹ, balẹ.
Wọn lawọn eeyan agbegbe naa ni wọn pe Ọkẹ lori aago rẹ pe awọn fura pe awọn olubi ẹda kan ti lugọ pamọ sinu igbo naa, wọn tiẹ ni baba agbẹ kan to lọ soko rẹ lo taju kan-an ri firifiri wọn, awọn jagunlabi naa ko ri i, ki baba yii too lọọ sọrọ ohun niluu, ti wọn fi pe Mohammed lati waa gbeja wọn.
Oloogbe naa ṣiṣe akin, o wọgbo tọ wọn loootọ, ṣugbọn ko too ri wọn, awọn apaayan naa ti kọkọ ri i, wọn si ṣina ibọn fun un, ni wọn ba pa a.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn si ti bẹrẹ iwadii lati mu awọn amookunṣika ẹda naa.
Lọwọ keji, eeyan meji lo kagbako iku ojiji nibi ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji ti wọn gbẹna woju ara wọn niluu Ogere ati Ipẹru, nijọba ibilẹ Ikẹnnẹ, lọjọ Furaidee.
Wọn ni ija aala ilẹ to waye laarin awọn olugbe ilu mejeeji ọhun lo di nnkan tawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun naa gba kanri, ti wọn si ba ara wọn ja le lori.
Nibi tawọn gende naa ti n yinbọn gbau gbau, wọn lọta ibọn ta atare lọọ ba Ọgbẹni Bayọ Rabiu, ti i ṣe mọlẹbi igbakeji olori ileegbimọ aṣọfin ipinlẹ Ogun tẹlẹri, Ọnarebu Dare Kadiri, ọta ibọn naa si pa a loju ẹsẹ.
Wọn loloogbe naa n dari bọ ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ pẹlu awọn mẹta kan ni ti aṣita ibọn fi da ẹmi ẹ legbodo yii.
Ọnarebu Kadiri ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o si ti parọwa sawọn ọdọ ilu Agọ-Iwoye ti wọn n leri p’awọn maa gbẹsan iku oro yii, pe ki wọn fọwọ wọnu, tori aforo-yaro ki i jẹ k’oro tan, o lawọn ti fa gbogbo ọrọ le Allah lọwọ.
Oyeyẹmi ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii bakan naa, awọn si maa tọpinpin ẹ dori okodoro, lati fiya jẹ awọn tajere ọrọ naa ba ṣi mọ lori.