Nibi ta a ti fẹẹ ta ọkan ninu ọkada mẹwaa ta a ji gbe lọwọ ti tẹ wa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn ọmọkunrin ọlọkada meji kan; Hammed Kazeem, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Ọlaniyi Taiwo toun jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn, lori ẹsun ole jija.

Ọkada Bajaj marun-un ti ko ni nọmba ni wọn gba lọwọ awọn afurasi mejeeji yii, gẹgẹ bi kọmiṣanna funleeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Falẹyẹ Ọlalẹyẹ, ṣe sọ.

Falẹyẹ ṣalaye pe ọwọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun (Anti-Cultism team) lo tẹ awọn afurasi yii lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lagbegbe Service, niluu Oṣogbo.

O ni lasiko ti wọn fẹẹ ta ọkan lara awọn ọkada ti wọn ji gbe ọhun ni aṣiri wọn tu, ti awọn araadugbo si ta awọn ọlọpaa lolobo.

Lasiko iwadii, awọn afurasi naa jẹwọ pe lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lawọn fọ ṣọọbu ọkunrin kan to n ta ọkada nidojukọ Baptist High School, Iree, ni nnkan bii aago mejila oru.

Awọn afurasi naa mu awọn ọlọpaa lọ si ile akọku kan to wa loju-ọna Iree/Iba, nibẹ ni wọn si ti ri awọn ọkada to ku.

Nigba ti ọkan lara wọn, Kazeem, n ba ALAROYE sọrọ, o ni iṣẹ ọkada loun ati Taiwo n ṣe, ṣugbọn nitori pe nnkan ko lọ deede lawọn ṣe ro o pe kawọn jale, o ni igba akọkọ si leleyii tawọn yoo ṣe iru ẹ.

Amọ ṣa, kọmiṣanna ọlọpaa ti sọ pe tiwadii ba ti pari lawọn afurasi mejeeji yoo kawọ pọnyin rojọ ni kootu.

Leave a Reply