Wọn nijọba Oyetọla fẹẹ rọ Ataọja Oṣogbo loye, lawọn araalu ba fẹhonu han 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Akọle oriṣiiriṣii bii, ‘ijọba Ọṣun, ẹ ma da wahala silẹ o, ẹ ma gbe igbesẹ lati yọ Ataọja Oṣogbo o’, ‘ẹ fura o, ijọba ipinlẹ Ọṣun fẹẹ da rukerudo silẹ’ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni awọn oloye, awọn ọmọ bibi ilu Oṣogbo, ninu eyi ti awọn ọdọ lọkunrin ati lobinrin wa, gbe lọwọ ti wọn fi n fẹhonu han ta ko bi wọn ṣe ni ijọba Oyetọla fẹẹ rọ Ataọja tilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Ọlanipẹkun, loye.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla yii, ni awọn eeyan naa fẹhonu han kaakiri ilu Oṣogbo.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ni wọn ti kọkọ ko ara wọn jọ si ile Oloye Jimoh Ibrahim, to jẹ olori fun gbogbo awọn adari agbegbe kọọkan niluu naa to wa ni OdiOlowo, niluu Oṣogbo. Latibẹ ni wọn ti fọn soju titi, ti wọn si n sọ pe ki ijọba ma dan an wo pe oun fẹẹ yọ Ataọja tilu Oṣogbo loye.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Oloye Ibrahim sọ pe awọn ti n gbọ hunrun hunrun nipa igbesẹ ti ijọba fẹẹ gbe lati rọ Ataọja loye.

O ni ohun ti wọn ni wọn fẹẹ tori ẹ yọ ọba yii loye ko se lori ẹjọ kan ti nọmba rẹ jẹ HOS/115/2022, eyi ti idile Oluwin, Ajibilu/Oyekomi pe ta ko bi kabiyesi ṣe wa lori ipo gẹgẹ bii Ataọja, ti ẹjọ naa si ti wa ni kootu.

Oloye yii ni igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe naa yoo da alaafia ilu Oṣogbo  ati ipinlẹ Ọṣun lapapọ ru. O ni bii igba ti wọn fẹẹ gbe igbesẹ lodi sofin ni, nitori ẹjọ naa ṣi n lọ lọwọ.

Bakan naa ni Ajaguna, to jẹ olori awọn afọbajẹ niluu Oṣogbo, Oloye Gabriel Ọparanti, sọ pe igbesẹ to tọna labẹ ofin ni wọn fi yan Ataọja ilu Oṣogbo, idagbasoke ti ko lẹgbẹ ni ọba naa si ti mu ba ilu Oṣogbo latigba to ti gbọpa aṣẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Akọwe iroyin Gomina Oyetọla, Ismail Omipidan, sọ pe ahesọ buruku ti ko lẹsẹ nilẹ ni, awọn eeyan kan sọ pe bi aja ko ba ri, ki i gbo, bẹẹ eti ọba nile, eti ọba loko, eeyan lo n jẹ bẹẹ. Wọn ni o ṣee ṣe ki awọn eeyan naa ti fura pe ijọba n gbe igbesẹ lati yọ ọba naa loootọ ni wọn ṣe tete mu ariwo bọnu, nitori koju ma ribi, gbogbo ara loogun rẹ.

Lẹyin eto idibo gomina to waye ninu oṣu Keje, ọdun yii, ti Oyetọla ti fidi rẹmi, to si ti han pe Ataọja pẹlu awọn eeyan ilu Oṣogbo ko ṣatilẹyin fun Oyetọla ni wahala ti n waye laarin wọn.

 

Leave a Reply