Faith Adebọla
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti leri pe ko sọna abayọ fawọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun mẹtadinlọgọrun-un tọwọ tẹ laipẹ yii, o ni dandan ni ki gbogbo wọn kawọ pọnyin rojọ latari ẹgbẹ buruku ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn n ṣe.
Inu otẹẹli kan ti wọn porukọ ẹ ni Uptown Hill Hotel, to wa ninu Ẹsiteeti Area 1, lagbegbe Mẹiran, nipinlẹ Eko, lọwọ ti ba awọn afurasi ọdaran ọhun ni aago meji ọganjọ oru Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti n ṣe pati rẹpẹtẹ lọwọ, wọn lawọn n ṣe eto gbigba ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle.
Odumosu ṣalaye fun AKEDE AGBAYE pe ẹnikan to fura si bawọn ọmọ naa ṣe n yọ foki foki kiri adugbo, tawọn kan gbe ọkada, tawọn kan bọọlẹ ninu kẹkẹ Marwa, nigba tawọn mi-in fẹsẹ rin, ninu okunkun birimu oru ọhun lo tẹ awọn ọlọpaa laago.
Nigba tawọn agbofinro fi maa debẹ, niṣe lawọn afurasi ẹlẹgbẹ okunkun naa pejọ biba sinu gbọngan nla otẹẹli naa ati ibi ti wọn ti n ta ọti, ti wọn dana ariya rẹpẹtẹ.
Kọmiṣanna ni awọn afurasi naa kọkọ dibọn pe ayẹyẹ ọjọọbi alaṣepọ lawọn n ṣe, awọn ki i ṣe ẹlẹgbẹ okunkun rara, ṣugbọn nigba ti wọn bẹrẹ si i tu gbogbo otẹẹli ti wọn wa naa wo, ni wọn ri awọn ẹru ofin kan.
Lara ẹru ti wọn ba nikaawọ wọn ni apo nla meji ti wọn ko igba ademu ati akufọ igba si loriṣiiriṣii, wọn tun ri apo mi-in ti oku adiyẹ tutu ati oku ẹja tutu kun inu ẹ, bẹẹ ni wọn ko aṣọ idanimọ ẹgbẹ okunkun alawọ yẹlo rẹpẹtẹ, fila bẹntigọọ alawọ yẹlo ati sokoto penpe alawọ kan naa sinu apo irẹsi nla meji kan. Orukọ ti wọn kọ sara awọn ẹwu naa ni: ‘Marllorca/Bucharest’, wọn si kọ ‘Bucharest/Flotila’ sawọn mi-in.
Yatọ sawọn ẹru wọnyi, awọn ọlọpaa tun ri iwe kan ti wọn to orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun to ṣẹṣẹ fẹẹ darapọ mọ wọn si, ‘Rẹjista FLT’ ni wọn kọ sẹyin iwe naa, pẹlu aworan amin idanimọ ẹgbẹ okunkun wọn lẹyin ẹ.
Wọn ti fi pampẹ ofin gbe gbogbo wọn, bẹẹ ni wọn ko awọn oṣiṣẹ ati alaṣe otẹẹli naa, ṣugbọn Odumosu ni ọtọ ni ẹjọ tiwọn.
O ni iwadii ti n lọ lọwọ lori ọrọ ọhun, o si da oun loju pe gbogbo wọn ati ẹsibiiti tawọn ba nikaawọ wọn lo maa fara han niwaju adajọ laipẹ