Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Latari ẹsun idigunjale ti wọn fi kan an, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Patrick Ejeh, niluu Abuja, nibi to fi ṣe ibuba.
Ejeh atawọn ẹmẹwa rẹ tawọn ọlọpaa ṣi n wa la gbọ pe wọn ja ọkọ Toyota Camry, alawọ pupa kan ti nọmba rẹ jẹ AKD 972 HR, gba pẹlu ìbọn lagbegbe Ìta-Onitan, Ọba-Ilé, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ kẹta, osu Kẹsan-an, ọdun yii.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, lawọn agbofinro tọ ipaṣẹ ọkọ ọhun de agbegbe kan ti wọn n pe ni Dutse Alhaji, Iyana Tipper Garrage, Abuja, nibi tọwọ ti tẹ Ejeh, ṣugbọn tawọn alabaaṣiṣẹ pọ rẹ sa lọ.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami ti ni iwadii awọn si n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa. Ọkunrin tọwọ tẹ ọhun lo ni yoo foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari.