Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ọrẹ mẹta kan, Adeyẹye Deji, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Adesuyi Damilọla, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ati Abiọdun Lekan, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ni wọn ti wa ni ahamọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, latari ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn n ṣe ẹgbẹ okunkun
Ẹiyẹ.
ALAROYE gbọ pe ọwọ awọn agbofinro tẹ wọn ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ kọkandinlọgbọn, osu Kẹwaa, ọdun yii, nibi ti wọn ti n ṣeto ati lọọ ṣe kọ lu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC kan to wa lagbegbe Abusọrọ, Ijọka, Akurẹ.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni ibọn agbelẹrọ meji lawọn ba ni ikawọ wọn lẹyin tọwọ tẹ wọn. O ni igbesẹ ti n lọ lati foju wọn bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.