O ma ṣe o, iyawo Tayọ Ayinde, olori awọn oṣiṣẹ Sanwoolu ku lojiji

Faith Adebọla

Inu ọfọ nla ni mọlẹbi atawọn ọrẹ Tayọ Ayinde, Olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, wa bayi o. Eyi ko sẹyin iku ojiji to pa iyawo ọkunrin naa, Doyin to wa lati mọlẹbi Ọjọra ilu Eko.

ALAROYE gbọ pe aarọ kutu ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla yii, ni obinrin naa dagbere faye.

A gbọ pe oṣu diẹ sẹyin bi ọmọ siluu London, to si ti pada si Naijiria pẹlu ọmọ tuntun naa.

Ko seni to ti i le sọ ohun to ṣokunfa iku arẹwa obinrin naa.

Awọn oloṣelu atawọn leekan leekan to ti gbọ nipa ajalu buruku naa ni wọn ti n ki mọlẹbi yii ku atẹmọra.

 

Leave a Reply