Aarẹ Buhari ti pada de lati London

Ọrẹoluwa Adedeji

Aarẹ Muhammadu Buhari ti pada siluu Abuja, lẹyin ọsẹ meji to lo ni London, ki awọn dokita le ṣayẹwo si ilera rẹ.

Papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe, lo balẹ si niluu Abuja.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, kede pe Aarẹ Buahri fẹẹ lọọ ri awọn dokita rẹ niluu oyinbo, ọsẹ meji ni yoo si lo.

Leave a Reply