Faith Adebọla
Wọn ni ko sẹni to le mọ’ya ọṣọ ju ọṣọ lọ, Gomina ipinlẹ Anambra, Ọjọgbọn Chukwuma Soludo, ti sọ pe oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, to ti figba kan ṣe gomina ipinlẹ Anambra ọhun fọdun mẹjọ, Ọgbẹni Peter Obi, ko ni i wọle sipo aarẹ to n dije fun ọhun lọdun 2023.
Soludo la ọrọ yii mọlẹ ninu apilẹkọ kan to fi lede lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun yii, eyi to pe akori rẹ ni: Asiko itan ree, mi o ni i dakẹ – Apa Ki-in-ni (History beckons and I will not be silent – Part 1).
O sọ lapa kan pe: “Ẹ jẹ ki kinni kan ye wa o. Peter Obi mọ p’oun o le wọle, ko si ni i wọle. O mọ ayo toun n ta, awọn naa mọ ọn, o si mọ pe a mọ ọn.
“Tori ayo oṣelu to n ta lọwọ ni ko fi pada sinu ẹgbẹ oṣelu APGA. Ootọ kikoro to wa nibẹ, tawọn kan maa n tori sọ pe ‘Ọlọrun o ni i jẹ’ ni pe eeyan meji pere, ẹgbẹ oṣelu meji pere ni wọn n dije funpo aarẹ ni ti gidi, gbogbo awọn yooku, ere ori itage lasan ni wọn n ṣe.
“Loootọ lọpọ eeyan ilẹ Amẹrika ko nifẹẹ Joe Biden, ẹni ọdun mọkandinlọgọrin, ati Donald Trump, ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin, to si jẹ pe awọn mejeeji yii ni wọn mupo iwaju lẹgbẹ oṣelu kaluku wọn, sibẹ, eyi o sọ pe ti wọn awọn mejeeji kalẹ lọdun 2024, ọkan ninu wọn naa lo ṣi maa wọle.”
Bẹẹ ni Soludo sọ o.