Faith Adebọla
Ba a da ogun ọdun, aa pe, ba a da ọgbọn oṣu, o n bọ waa ku ọla, ọjọ tawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, fẹnu ko si lati ṣide eto ipolongo ibo fun oludije funpo aarẹ wọn, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla yii, tilu tifọn si layẹyẹ naa waye niluu Jos, ipinlẹ Plateau.
Lati aṣaalẹ ọjọ Aje, Mọnde, to ṣaaju, ni papa iṣere Rwang Pam Stadium ti pawọ da bii ọga, ti wọn ti ṣe gbogbo ayika rẹ lọṣọọ pẹlu awọn aworan Tinubu ati Shettima, iwe ipolongo ibo alẹmọgiri, asia ẹgbẹ APC, asia ipolongo ibo ti wọn yaworan Tinubu ati Kashim Shettima ti i ṣe igbakeji rẹ si, awọn ododo oloorun didun, atawọn nnkan ẹyẹ mi-in.
Bakan naa ni eto aabo ti wọn ro lagbara layiika papa iṣere naa, ati kaakiri awọn ọna marosẹ, yoo ti mu kawọn araalu atawọn alejo fura pe eto akanṣe kan fẹẹ waye. Wamuwamu lawọn ẹṣọ alaabo loriṣiiriṣii duro bii ologun, awọn ṣọja, awọn ọmoogun oju ofurufu, awọn ọlọpaa, Sifu Difẹnsi, titi kan awọn ẹṣọ alaabo oju popo, ti wọn n pe ni Road Safety, ko gbẹyin, gbogbo wọn ta mọra nibẹ.
Olori orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, lo lọọ ṣiṣọ eegun eto ipolongo naa, to si fi i lọlẹ.
Nigba ti Buhari yoo fi jade ninu ọkọ ofurufu to gbe e wa, o ti wọṣọ ẹgbẹjọda akanṣe ti wọn ran fun eto ọhun, aṣọ naa lo si wa lọrun ọpọ awọn eekan eekan ẹgbẹ APC atawọn gomina wọn, titi kan awọn oludije, Tinubu ati Shettima.
Agbada ni gbogbo wọn fi da, ti wọn si wọ ọ lori imura wọn. Niwaju ọkọọkan agbada naa, wọn kọ akọle sibẹ pe: “APC, Jagaban, ẹ kaabọ si Plateau,” wọn si ya aworan Tinubu, Shettima, ati Oludari agba fun eto ipolongo ibo wọn, to tun jẹ gomina ipinlẹ Plateau lọwọlọwọ, Ọmọwee Simon Lanlong, ati maapu ipinlẹ Platueau si i.
Bo tilẹ jẹ pe Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ati awọn minisita kan, bii Rauf Arẹgbẹṣọla ati minisita tẹlẹ, Rotimi Amaechi, ko yọju sibi eto naa. Lara awọn eeyan pataki to pesẹ sibẹ ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla, ti Eko, Babajide Sanwo-Olu, alaga APC, Abdullahi Adamu, awọn oloye ẹgbẹ atawọn ọmọ igbimọ ipolongo ibo naa.
Áṣọ funfun balau kan ni Tinubu wọ, o si de fila pupa to ni aworan tawọn eeyan ti mọ ọn mọ si i, bẹẹ ni iyawo rẹ, Olurẹmi, jokoo sẹgbẹẹ rẹ, lori aga ọlọla funfun ti wọn pese fun wọn.
Ero rẹpẹtẹ lo wa ni papa iṣere naa, ti wọn waa fi atilẹyin wọn han.
Pẹlu ayẹyẹ yii, ipolongo ibo aarẹ fun Tinubu yoo bẹrẹ ni pẹrẹu, ọjọ kẹtala, oṣu Keji si ni wọn lawọn maa fi adagba eto naa rọ, lẹyin aṣekagba ayẹyẹ to maa waye l’Ekoo.