Faith Adebọla, Lagos
Ọkan ninu awọn aṣofin ipinlẹ Eko to n ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Mushin keji, Ọnarebu Ọlawale Ọlayiwọla Abdul-Subor, tawọn eeyan mọ si ‘Ó mì tìtì,’ ti jade laye.
Ba a ṣe gbọ, ọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgọta (64) yii dagbere fawọn mọlẹbi rẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lati tẹle oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lọ siluu Jos, nipinlẹ Plateau, nibi ti ayẹyẹ ifilọlẹ eto ipolongo ibo aarẹ Tinubu ati igbakeji ẹ, Kashim Shettima, ti waye, lọjọ keji, iyẹn Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla yii.
Wọn ni wọn ti dọhun-un layọ atalaafia, eto ipolongo naa si bẹrẹ bi wọn ṣe ṣeto rẹ, ṣugbọn lori iduro toun atawọn yooku rẹ wa, ti wọn ti n kọrin, ti wọn si n da si eto to n lọ ọhun, ni nnkan ti yipada biri fọkunrin naa, wọn lo sọ fawọn ẹgbẹ rẹ pe ooru n mu oun lati inu wa, o si n laagun lakọlakọ.
Ki wọn too ṣẹju peu, wọn lojiji laṣofin yii ṣubu lulẹ, lawọn to wa nitosi rẹ ba gbe e digbadigba, wọn sare gbe e lọ sinu ọkọ agbokuu-gbalaaye kan to wa nitosi lati pese itọju pajawiri fun un, lẹyin naa ni wọn gbe e lọ sileewosan aladaani kan to ko fi bẹẹ jinna sibẹ, ṣugbọn ki wọn too debẹ, akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin, ‘O mi titi’ ti lọ.
Oludamọran pataki si gomina Babajide Sanwo-Olu lori ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Bakan naa ni Ọnarebu Fẹmi Saheed, loju opo ayelujara Wasaapu rẹ kede iku ojiji yii.
A gbọ pe oṣu Kejila, ọdun yii, ni ọmọ aṣofin yii kan fẹẹ ṣeyawo, ti wọn si ti n palẹmọ ayẹyẹ mareeji naa labẹnu.
Ọjọ kejila oṣu Kẹta, ọdun 1964, ni wọn bi oloogbe yii, ṣugbọn ilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, lo ti ṣe kekere rẹ.
Wọn yan an sipo oludamọran pataki fun Gomina Bọla Tinubu lori eto igbokegbodo ọkọ lasiko iṣejọba rẹ nipinlẹ Eko, o si wọle sipo aṣofin ipinlẹ naa lọdun 2015, saa ẹlẹẹkeji rẹ lo n pari lọ tiku fi de yii.
Oun ni Alaga igbimọ alabẹ-ṣekele ile aṣofin naa lori ọrọ to jẹ mọ eto ijọba ibilẹ l’Ekoo.