Lori ọrọ ti ko to nnkan, oni-Maruwa lu ọrẹ ẹ pa l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade ati Faith Adebọla

Ọkunrin oni-Marwa ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Festus Akintẹlurẹ, ti dero ahamọ nipinlẹ Ondo, latari bi wọn ṣe lo fibinu lu oni-Maruwa ẹlẹgbẹ rẹ kan, Titus Adebayọ, ẹni ọdun marundinlogoji, to si pa a lasiko ija ajaku-akata kan to waye laarin awọn mejeeji lagbegbe Oke-Aro, niluu Akurẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, Oṣu Kọkanla yii.

 

ALAROYE gbọpe ọrọ imọtoto ayika lo dija silẹ. Wọn lawọn to n fi kẹkẹ Maruwa ṣiṣẹ aje lagbegbe naa ṣepade, wọn si fẹnu ko pe kawọn pawọ-pọ ṣe atunṣe oju-ọna tawọn n fi kẹkẹ na, wọn fẹẹ di awọn koto-gegele to wa lọna naa.

Ọjọ Satide ọhun ni wọn fẹnu ko si, ṣugbọn Oloogbe yii ko yọju sibẹ titi tawọn ẹlẹgbẹ rẹ fi pari iṣẹ ọhun. Lẹyin tiṣẹ naa pari ni wọn ri Titus nibi to gbe n yan fanda kiri, eyi ni wọn lo fa isọrọ-sira-ẹni laarin awọn mejeeji.

Fa-n-fa-a yii ni wọn lo pada dija laarin wọn tawọn mejeeji fi wọya ija, wọn si bẹrẹ si i gba ara wọn lẹṣẹẹ, ṣugbọn o jọ pe ọwọ Festus le ju ti Titus lọ, tori lojiji to gba a lẹṣẹẹ kan ni wọn lo ṣubu lulẹ, to si daku.

Wọn sare gbe ọkunrin naa digbadigba lọ sileewosan kan to wa nitosi ibẹ, nibi to ti pada laju saye fun igba diẹ, ko too di pe o tun pada ku laaarọ kutukutu ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla yii.

Lẹyin eyi ni wọn lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa ‘B’ Difiṣan l’Oke-Aro leti, ti wọn si ṣeto ati fi pampẹ ofin gbe ọkunrin Festus abẹṣẹẹ-ku-bii-ojo ọhun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami ni awọn ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori ohun to le ṣokunfa iku Titus, afurasi naa si ti n ṣalaye ara ẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ.

O ni kete ti abọ iwadii naa ba ti jade ni afurasi ọhun yoo foju ba’le-ẹjọ.

Leave a Reply