A ṣetan lati yọ ipinlẹ Eko ninu igbekun afọbajẹ to sọ ọ di ogun ini rẹ – PDP

Monisọla Saka

Pẹlu idunnu ati ayọ lawọn ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), fi ṣe iwọde niluu Eko, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, nibẹ ni wọn ti lawọn maa fẹyin ẹgbẹ oṣelu APC janlẹ lasiko ibo gbogbogboo ọdun 2023. Wọn ni asiko ti to fawọn lati gba ipinlẹ Eko ninu igbekun afọbajẹ to ti sọ ipo naa di oye idile ti wọn wa.

Awọn aṣaaju ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun ni wọn sọ eleyii lasiko iwọde ti wọn pe ni ‘Ọjọ Aburanda’ (Umbrella day), eyi ti wọn ṣe ni imurasilẹ fun ibo ọdun to n bọ. Lati agbegbe Fadeyi, lọ si Maryland, opopona Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni iwọde naa ti waye. Wọn lawọn ti ṣetan lati fa gbogbo ibo Eko le Atiku Abubakar ti i ṣe oludije dupo aarẹ ẹgbẹ wọn lọwọ.

Nibi iwọde ipolongo ibo ti wọn ṣe loju titi marosẹ Ikorodu si Eko yii lawọn jankan jankan ninu ẹgbẹ yii bii oludije dupo gomina nipinlẹ naa, Abdulazeez Adediran, tawọn eeyan mọ si Jandor, igbakeji ẹ, Funkẹ Akindele, awọn ọmọ igbimọ ẹgbẹ bii Adukẹ Marina, Dokita Bimbọ Ogunkelu, alaga ẹgbẹ PDP tẹlẹri nipinlẹ naa, Captain Tunji Shelle, Philip Aivoje, Ọgbẹni Deji Doherty, Tọlagbe Animashaun atawọn mi-in bẹẹ ti ga aburanda lori gẹgẹ bii ami idanimọ ẹgbẹ wọn. Alaga ikọ ipolongo ibo fun Atiku ati Okowa, Ọgbẹni Adedeji Doherty, atawọn oloye mi-in ninu ẹgbẹ wọn ni wọn ṣaaju iwọde naa.

Agbẹnusọ ẹgbẹ wọn tẹlẹ, Ọgbẹni Taofik Gani, sọ pe, “Akoko to wayi lati fẹyin Tinubu janlẹ l’Ekoo. Nigba ti Ọlọrun si maa kuku ṣe e, oun funra ẹ n dupo aarẹ, yoo fi le dun nigba ti awa pẹlu ẹ ta a di jọ n figagbaga ba gbe e lulẹ lasiko ibo.

Lasiko to n ba awọn eeyan sọrọ nigba ti wọn de agbegbe Maryland, Doherty ni, irin Aburanda tawọn n rin yii tumọ si ami iṣọkan, erongba rẹ si ni lati fi han awọn eleto idibo pe awọn ti gbaradi, bẹẹ inu iṣọkan lawọn wa lati fun Naijiria ni ireti rere bi wọn ba dibo yan awọn.

“Ami irẹpọ ati iṣọkan ni Aburanda yii lati da awọn eeyan wa pọ, yala nipa ẹsin tabi ẹya, fun Atiku ati Okowa. Eleyii n ṣafihan ọkan ṣoṣo ta a jẹ nipinlẹ Eko, ati lorilẹ-ede Naijiria.

Aroko ni eleyii tun n pa ranṣẹ sawọn ijọba to wa nipo bayii lati jẹ ki wọn mọ pe ni kete ti ijọba wa ba depo lọdun 2023, la maa fi ẹmi ifẹ ati irẹpọ sọ orilẹ-ede yii di ọkan ṣoṣo.

‘‘Ọga wa, Atiku Abubakar, ti ṣeleri pe oun yoo ko tolori tẹlẹmu mọra ninu iṣejọba oun toun ba wọle. Fun idi eyi, Peter Obi, ẹgbẹ Labour, Rabiu Kwankwaso, ti NNPP, ati Bọla Tinubu, ẹgbẹ oṣelu APC, gbọdọ ṣetan lati fọwọsowọpọ ba a ṣiṣẹ ni. Gbogbo eeyan lo maa ko mọra ti wọn jọ maa ṣiṣẹ pọ, ti iṣọkan ba si ti wa, kekere niyoku.

‘‘Awọn ọmọ Naijiria ti tọ ẹgbẹ PDP ati APC wo, wọn si ti mọ iyatọ, ṣe b’obinrin o ba dan ile ọkọ meji wo, ko ni i mọ eyi to daa, ẹ jẹ ki wọn tun faaye gba PDP lẹẹkan si i, ka le raaye ṣe atunṣe sawọn kudiẹ kudiẹ wa”.

Bakan naa ni igbakeji adari ipolongo ibo wọn, Tunji Shelle, fọwọ sọya pe Atiku lo maa wọle ibo 2023, o ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bii eeyan ti ori ẹ pe daadaa, to ni alaafia, eeyan to maa n ko ni mọra, ti ọrọ si da ṣaka lẹnu ẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, Akọwe iroyin fun ẹgbẹ PDP ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Hakeem Amọdẹ, ni ipinlẹ Eko ati Naijiria yoo daa labẹ iṣejọba awọn. Bẹẹ lo ṣeleri pe ijọba awọn n bọ waa yi igbe aye awọn eeyan pada ni, ki i ṣe ijọba ajẹnirun.

Leave a Reply