Gbenga Amos, Abẹokuta
Akolo ọlọpaa, lẹka ileeṣẹ wọn to wa niluu Ipokia, nijọba ibilẹ Ipokia, ipinlẹ Ogun, ni gende ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, AbdulRasheed Yinusa, ti n jẹwọ ẹṣẹ ẹ bayii, o ni loootọ loun ji ọkada Bajaj pupa kan niluu Ajegunlẹ, ibi to ti wa ẹni to maa ta a fun ni gbanjo lawọn agbofinro ti mu un.
Ọga agba ẹṣọ alaabo So-Safe, Kọmandanti Sọji Ganzallo, to sọrọ yii ninu atẹjade kan ti Alukoro wọn, Moruf Yusuf, fi lede lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla yii. O ni awọn kan ni wọn kegbajare wa sọfiisi awọn to wa niluu Ipokia pe ole ti ji ọkada kan gbe sa lọ, wọn ni ile kan to wa ni Ọgọsa, l’Ajegunlẹ, ni wọn ti ji ọkada ti wọn pe nọmba rẹ ni AAA 648 QL ọhun.
Oju-ẹsẹ ni Eria Kọmanda So-Safe n’Ipokia ti ko awọn ọmọọṣẹ rẹ sodi, wọn si bẹrẹ si i tọpasẹ afurasi ole naa, gbogbo ọkada to jọ eyi ti wọn n wa ni wọn n ṣayẹwo si, iṣẹ takuntakun si ni wọn ṣe ki olobo too ta wọn pe ki wọn tete wa afurasi ọhun lọ siluu Atan-Iju, ibẹ naa si lọwọ ti to o pẹlu ọkada to ji, nibi to ti n wa bo ṣe maa ta a.
Yinusa, ti wọn lo n gbe adugbo Ifẹtẹdo, ni Ọgọsa, Ajegunlẹ, ko la awọn ẹṣọ naa loogun nigba ti wọn mu un, wọn ni lẹrọ lo jẹwọ, o loun ji ọkada naa ni, oun si mọ-ọn-mọ ji i ni, tori oun ti foju si alupupu naa lara tipẹ.
Ganzallo ni awọn ti pari iwadii tawọn, awọn si ti fa afurasi ọdaran yii ati ọkada to ji gbe le awọn ọlọpaa lọwọ ki wọn le tubọ tanna ofin wo iṣẹlẹ yii, o ni Yinusa maa too fara han niwaju adajọ laipẹ.