Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo wọ baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọta nni, Joseph Ojo, to dana sun awọn ọmọ iyawo rẹ marun-un, ti mẹta si ku ninu wọn, lọ sile-ẹjọ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.
Ọkunrin to jẹ ọmọ bibi ilu Ondo ọhun ni wọn fẹsun mẹta ọtọọtọ kan lasiko to n fara han ni kootu Majisireeti kin-in-ni to wa l’Oke-Ẹda niluu Akurẹ.
Iṣẹlẹ yii lo waye l’Ojule kẹtadinlogoji, adugbo Ayesanmi, Odojọmu, Ondo, ni nnkan bii aago mẹta oru ọjọ karun-un, osu Kọkanla, ọdun 2022.
Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan ọkunrin to n ṣiṣẹ igi gẹdu ọhun ni pe o dana sun, Tọpẹ Akinfọlayan, ẹni ọdun mẹrinla, Aanu Akinfọlayan, ẹni ọdun mẹwaa ati Tayọ Akinfọlayan ọmọ ọdun mẹjọ, pẹlu bo ṣe da epo bẹntiroolu le wọn lori, to si tun sana si i, eyi to pada ṣokùnfà iku awọn ọmọ mẹtẹẹta.
Ninu ẹsun keji, wọn ni olujẹjọ naa tun gbiyanju lati ṣeku pa Esther Ojo atawọn ọmọ rẹ meji, Bisọla Akinfọlayan ati Tobi Akinfọlayan, nipa didana sun wọn.
Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan Ojo pe o mọ-ọn mọ dana sun ọkada Honda kan to jẹ ti Ṣeun Afọlayan, eyi ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira (600,000).
Awọn ẹsun ọhun ni Agbefọba, Nelson Akintimẹhin, ni o lodi labẹ abala Okoo-le-lọọọdunrun din mẹrin (316), Okoo-le-lọọọdunrun (320) ati Oji-le-nirinwo le mẹta ((443) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Akintimẹhin bẹbẹ fun fifi afurasi ọdaran naa pamọ sinu ọgba ẹwọn titi ti kootu ọhun yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Agbejọro olujẹjọ, Ọmọọba Adekunle, ninu ọrọ tirẹ ni o yẹ ki ile-ẹjọ fun onibaara oun laaye ko le fesi lori ẹbẹ ti agbefọba fi siwaju adajọ.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Musa Al-Yunnus ni ki Ojo ṣi lọọ maa ṣere ninu ọgba ẹwọn na gẹgẹ bii ibeere agbefọba.
Lẹyin eyi lo sun ijokoo mi-in si ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun 2023.