Gbenga Amos, Ogun
Ibinu ko mọ p’olowo oun ko lẹsẹ nilẹ. Beẹ lọrọ ri fun baale ile ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Oluwaṣẹgun Ọmọtọṣọ Ebenezer, ti ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa latari ẹsun pe o fibinu la agadagodo mọ iyawo rẹ, Olubukọla Ọmọtọṣọ, lori nigba ti wọn jọ n ṣe gbolohun asọ, obinrin ẹni ọdun mejilelogoji naa si gbabẹ ku patapata.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lawọn ọlọpaa lọọ fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran naa, nigba ti ẹgbọn oloogbe lọọ fẹjọ ẹ sun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Kemta, l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun. O ni ọkọ aburo oun ti luyawo ẹ pa nibi ti wọn ti n ja lori ọrọ ti ko to nnkan.
Obinrin naa ni niṣe lọkọ yii la agadagodo nla ti wọn fi n ti geeti ile wọn mọ iyawo rẹ yii lori, ti ori naa si bẹjẹ, lobinrin naa ba mu’dii lọọlẹ.
O lawọn eeyan to wa nitosi ni wọn sare gbe e digbadigba lọ sileewosan ijọba, Federal Medical Centre (FMC), to wa lagbegbe Idi-Aba, l’Abẹokuta. Awọn dokita gbiyanju lati doola ẹmi ẹ, wọn fun un ni itọju pajawiri, ṣugbọn bi wọn ṣe n tọju ẹ lọwọ naa lo mi eemi ikẹyin.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe obinrin naa laju diẹ nigba to wa lọsibitu, wọn ni pẹlu irora naa lo dọgbọn fi ọrọ ranṣẹ sawọn mọlẹbi ẹ kan lori aago pe ọsibitu loun wa bayii o, oun atọkọ oun lawọn n ja to fi la agadagodo mọ oun lori, eyi lo si sọ oun dero ọsibitu, oun o ti i mọ’bi tọrọ naa le ja si o, ṣugbọn to ba fi ja siku, ki wọn mọ pe Ṣẹgun lo pa oun o, oun ni ki wọn beere iku oun lọwọ ẹ.
Kete to pari ifohunranṣẹ ti wọn n pe ni voice note ọhun, to si fi i ṣọwọ, ni wọn lo dakẹ.
Wọn ni bi baale ile ọran yii ṣe gbọ nipa ifohunranṣẹ ọhun nibi to ti n ronu irọ to maa fi bo iwa buruku to hu mọlẹ, o ri i pe aṣiri naa ko bo mọ, niṣe lo ba ẹsẹ rẹ sọrọ, o na papa bora.
Eyi lo mu kawọn ọlọpaa atawọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ si i wa a, wọn tọpinpin ibi to le sa pamọ si, iṣẹ gidi si ni DPO teṣan Kemta, SCP Adeniyi Adekunle, atawọn ẹmẹwa rẹ ṣe ki olobo kan too ta wọn pe jagunlabi yii ti lọ sabule Akinṣeku, wọn nibẹ lo fara ṣoko si. Awọn ara abule naa ko tiẹ fura pe ajoji ọdaran kan lo n ba awọn gbe, tori abule ọhun jinna gidi siluu Abẹokuta, ibẹ naa si lọwọ ti ba a nigbẹyin.
Alukoro Oyeyẹmi ni iwadii tawọn ṣe fihan pe loore-koore ni ija ati aawọ maa n waye laarin tọkọ-taya yii latẹyinwa, wọn ni ko sohun meji to saaba n dija ọhun silẹ ju pe iyawo ọkunrin yii da ileewe pamari kan silẹ, tori ileewe olukọni lo lọ to gboye NCE jade, wọn nileewe naa si n ṣe daadaa. Ṣugbọn gbogbo igba lọkọ rẹ ti ko le fidi igo kọ ‘o’, ti wọn lo n ṣiṣẹ kafinta yii maa n ba a ja pe oun loun fẹẹ maa ṣakoso ileewe naa, tori ọkọ lolori aya, ṣugbọn ti obinrin yii ko gba fun un. Eyi ni wọn lo mu ki ọkọ naa maa lu iyawo rẹ lalubami lọpọ igba ti wọn ba ti sọrọ naa dija.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ ki wọn taari ọkọọyawo alajangbila si ẹka ti wọn ti n wadii ẹsun iwa ọdaran abẹle lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Eleweẹran, l’Abẹokuta.
O lawọn maa foju Ebenezer bale-ẹjọ laipẹ.