Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, lobinrin ẹni ogoji ọdun kan, Bọsẹ Abimbọla, ti n kawọ pọnyin rojọ lori ẹsun pe o fọ ṣọọbu awọn eeyan kan lagbegbe Oke-Igbala, nibi to ti ji ọpọlọpọ ẹru olowo iyebiye ko.
Ẹsun bii mẹfa ni wọn fi kan olujẹjọ ọhun lasiko to n fara han ni kootu lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja.
Ṣọọbu obinrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Toyin Kunle ni wọn lo kọkọ lọọ fọ, to si ji awọn ẹru olowo iyebiye ko nibẹ ko too tun kọja lọ si sọdọ awọn mẹta mi-in, to si tun ja wọn lole awọn nnkan olowo nla.
Apapọ ẹru ti olujẹjọ ọhun ji ko ninu ṣọọbu awọn mẹrẹẹrin to ja lole ni wọn lo to bii miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna mejidinlọgọta Naira (#1, 058,000).
Agbefọba, Gbenga Akinsulirẹ, ṣalaye pe gbogbo ẹsun ti wọn ka si afurasi naa lẹsẹ lo ta ko iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Lẹyin ti olujẹjọ ti ni oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, agbefọba bẹbẹ fun sisun igbẹjọ siwaju ko le lanfaani lati ṣayẹwo si iwe ẹsun ti wọn fi kan an daadaa.
Agbẹjọro fun olujẹjọ, Amofin Akinnugba Hawkins, bẹbẹ fun gbigba beeli onibaara rẹ, o si ṣeleri lati ṣeto oniduuro ti yoo duro fun un.
Onidaajọ C. E. Ijeh faaye beeli Bọsẹ silẹ pẹlu miliọnu kan Naira ati oniduuro meji. Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun to n bọ, lo sun igbẹjọ mi-in si.