Gbenga Amos, Ogun
Ọrẹ o si mọ, ka rẹni ba rin lo ku, ọrọ yii ti ja si ootọ ninu iṣẹlẹ ibanujẹ kan to waye niluu Owode, nibi ti Pasitọ Felix Ajadi, Idowu Abel ati Clement Adeniyi, ti tan ọrẹ wọn, Muyiwa Adekunle, ẹni ọdun mọkandinlogoji, lọ sinu oko lẹyin ti wọn jọ ṣe faaji tan, ti wọn si da baba agbalagba naa dubulẹ, wọn dumbu rẹ bii ẹran Ileya, lẹyin ti wọn si ti yọ ẹya ara ti wọn fẹẹ ta lara ẹ tan, wọn ṣa oku ẹ si wẹwẹ, ni wọn ba da yeepẹ bo o, amọ ọwọ ti tẹ wọn.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, o ni ẹgbọn ọkunrin to kagbako iku airotẹlẹ naa, Oluwaṣeyi Adekunle, lo mu ẹjọ wa si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Owode Yewa, pe ṣe lawọn kan ṣadeede wa aburo oun ti laduugbo, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla yii lo lawọn ri i kẹyin. Ọjọbọ, Tọsidee, lọjọ naa bọ si, bẹẹ ko lọ ode alọọde bẹẹ ri, wọn lawọn kan ri i nibi toun atawọn ọrẹ ẹ ti n ṣe faaji, ti wọn n fi ọti bia atẹran dindin jaye ori wọn nile ọti kan lọjọ naa ni, ibi tawọn si gburoo rẹ mọ niyẹn.
Lọgan ti wọn rojọ yii fun DPO teṣan Owode Yewa, o paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ atawọn ọtẹlẹmuyẹ lati bẹrẹ itọpinpin. Idowu Abel, ti wọn loun ati Muyiwa yii jọọ ṣe ‘Lankẹ ọmu’ titi dọwọ irọlẹ ọjọ naa ni wọn kọkọ fura si, oun lawọn ọlọpaa si kọkọ lọọ gbe lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla yii. Wọn tiẹ lafurasi ọdaran yii lo waa pe oloogbe ọrẹ rẹ ọhun nile pe ko jẹ kawọn lọọ ṣe faaji diẹ nigboro, kawọn ta-nnkan’ara, wọn o si ṣẹṣẹ jọ maa lọ ode bẹẹ, ṣe ọrẹ ki i ya ọrẹ, akobani ki i ya ara wọn.
Ni tọlọpaa ni Abel ti jẹwọ pe loootọ ni, oun loun lọọ pe ọrẹ oun pe ko jẹ kawọn jọ jade, o lọrẹẹ oun gidi ni, kori-kosun lawọn jọ n ṣe, oun loun si ṣe e lalejo lọjọ naa, t’oun sanwo ọti tawọn mu, lai mọ pe ifẹ a fadiẹ o denu lo ṣe, oore, bii ẹni fọgẹdẹ sabẹ ẹbiti fẹranko ni owo to na lọjọ naa.
Wọn bi i leere pe lẹyin ti wọn muti tan, tawọn mejeeji jọ jade, ibo lọrẹ imulẹ ẹ yii waa wọlẹ si, ibẹ ni jagunlabi ti n wolẹ ṣu-un bii akágbàá, lo ba jẹwọ pe oun atiẹ jọ lọọ sọdọ ọrẹ kẹta wọn, iyẹn Clement Adeniyi, ninu oko rẹ, tori iyẹn ti n reti awọn gẹgẹ bii eto ati adehun, ibẹ lawọn pa Muyiwa si, tawọn si kun un si wẹwẹ, awọn yọ ẹya-ara tawọn nilo lara ẹ bii ori, ọwọ, ọkan ati ẹsẹ, lawọn ba wa koto kuṣẹkuṣẹ kan, awọn si bo iyooku ara ti wọn ti ge lekiri-lekiri naa, mọlẹ.
Njẹ kin ni wọn fẹẹ fi ẹya-ara eeyan ṣe ti wọn fi sọ ọrẹ wọn dẹran namọ, o lawọn fẹẹ ta a ni, babalawo kan to ni wọn n pe ni Boko, amọ Akeem lorukọ ẹ gan-an, lo bẹ awọn lọwẹ pe ti awọn ba le ba oun wa awọn ẹya-ara eeyan ti wọn ṣa jọ ọhun, oun maa fun wọn lẹgbẹrun lọna igba Naira (N200,000), o loun fẹ fi i ṣetutu ọla ni, o si ti san ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira (N80,000) fawọn, lati fihan pe eyi ki i ṣe ọrọ apara rara, o ni ti wọn ba ti pari iṣẹ naa, ti wọn ko awọn kinni naa wa perepere, balansi ẹgbẹrun lọna ọgọfa Naira (N120,000) ti n duro de wọn, ko si lọ-ka-bọ nibẹ rara.
Yooba si bọ, wọn lẹni ti yoo lo ori ahun, ti yoo lo ẹsẹ ahun, odidi ahun ni tọhun yoo ra niyẹn, eyi lo mu kawọn kuku yẹju ọrẹ awọn, lati yọ ẹya-ara ẹ ta.
Alaye ti Abel ṣe yii lo mu ki wọn wa Clement lawaakan, Abel naa lo juwe ile ẹ atibi ti wọn ti le tete ri i ti ko ba si nile fun wọn, ọwọ si ba a.
Wọn lawọn mejeeji ti mu awọn agbofinro denu oko ti wọn pa ọrẹ wọn si ọhun, wọn si ba ageku oloogbe ti wọn bo mọlẹ ọhun nibẹ, wọn ri ada ati ọbẹ ti wọn fi da ẹmi ẹni ẹlẹni ọhun legbodo pẹlu, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ọ lo ri loootọ.
Awọn afurasi naa jẹwọ pe awọn ti ko awọn ẹya-ara ti wọn fẹẹ ta naa lọọ fun babalawo afeeyan-ṣowo yii, ṣugbọn ko ti i fawọn ni balansi owo iṣẹ awọn ti akara ọrọ yii fi tu sepo.
Wọn tun wa babalawo naa lọ sile rẹ, ṣugbọn wọn o ba a, o jọ pe ara ti fu u, o si ti na papa bora.
Bẹẹ lawọn ọlọpaa tun lọọ fi pampẹ ofin gbe Pasitọ Felix Ajadi, tori wọn darukọ ẹ ninu alaye wọn, wọn loun lo fi oloogbe ti wọn fẹmi ẹ ṣofo naa mọra pẹlu awọn ti wọn pa a, wọn loun lo pilẹ ọrẹ rẹrun-rẹrun ti wọn jọ n ṣe, ati pe ileewe agba kan naa ni pasitọ yii ati ọkan ninu awọn afurasi naa Abel, jọ lọ.
Ṣa, akolo ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to n tọpinpin iwa ọdaran abẹle, lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleweeran, Abeokuta, lawọn afurasi mẹtẹẹta yii wa bayii, iwadii to lọọrin si ti n lọ lori wọn.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti lawọn maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ, tori ọrọ ti sọ ara ẹ, wọn ti fẹnu ara wọn jẹwọ iṣẹ laabi wọn, ohun to ku ni ki adajọ gbọ alaye wọn, ko si da sẹria to tọ fun wọn labẹ ofin. Bakan naa lo ni ẹgbẹrun Saamu babalawo naa ko le sa mọ awọn lọwọ, o lawọn maa wa a ri dandan, awọn yoo si mu un debi ti imi ẹṣin gbe dunlẹ tọwọ ba to o.