Jọkẹ Amọri
Ko si ariyanjiyan mọ bayii pe awọn ajinigbe ati afẹmiṣofo ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Hausa ti wọ ilẹ Yoruba gidigidi, mo si n lo asiko yii lati kilọ fun gbogbo eeyan lati maa wa lojufo, ki wọn si maa ṣọra wọn gidigidi. Eyi ni ọrọ ti ọmọkunrin kan ti fidio rẹ n ja ran-in lori ayelujara sọ nigba ti Ọlọrun ko o yọ lọwọ awọn ajinigbe ti wọn iba fi i ṣowo, ti wọn fẹẹ gbe wọn lọ.
Ọkunrin naa ṣalaye lede oyinbo bayii pe ‘‘Ni gbogbo alẹ ti mo ba ti pari eto ẹkọ ti mo maa n ṣe fawọn eeyan ni gbogbo ibi ti mo ni awọn ile ẹkọ wọnyi si ni Ajah, Jakande, Elegushi Marwa tabi Bananna Island, nitori mo ni oriṣiiriṣii ibi ti mo ti n kọ awọn eeyan nipa bi wọn ṣe le kọ awọn ere keekeeke ni gbogbo ọjọ ninu ọsẹ. Nitori pe bii aago meje ni mo maa n saaba pari awọn ẹkọ ti mo n kọ awọn eeyan yii, sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ti maa n wa, paapaa ju lọ ni Third Mainland Bridge, eyi maa n jẹ ki n pẹ ki n too dele, o le to bii wakati meji si meta, o si maa n ni mi lara lati maa jokoo sinu moto ti sun-kẹrẹ fa kẹrẹ ba ti wa.
‘‘Nigba mi-in, niṣe ni mo maa paaki mọto mi si ibi ti mo ba ti kọ wọn l’ẹkoo, ti ma a si lọọ gbe e lọjọ keji tabi lopin ọsẹ.
‘‘Ṣugbọn ni ọjọ yii, mo ṣiṣẹ to pọ gan-an, o ti waa rẹ mi, mo waa pinnu pe ki n wọ mọto ero, bo ba si ṣe wu ki sun-kere-fa-kẹrẹ pọ to, ma a ṣaa dele, eyi yoo si tun fun mi lanfaani lati sinmi ninu mọto ju ki n wa ọkọ funra mi lọ.
‘‘Mo gbọ mọto kan to n pe Iyana Oworo. Nigba ti mo wọnu mọto naa, mo bẹrẹ si i gbọ oorun buruku kan to le gan-an. Ṣugbọn ẹnikẹni to ba ti ni ẹkọ nipa iṣẹ ologun tabi to sun mọ wọn, to ba ti gbọ iru oorun yii yoo ti mọ pe awọn afẹfẹ gaasi kan wa to jẹ pe teeyan ba ti fa a simu, yoo jẹ ki oluwarẹ sun tabi ko ma lagbara mọ, iru rẹ ni oorun ti mo n gbọ yii. Bi mo ṣe wọnu mọto naa ti mo berẹ si i gbooorun yin ni mo yọ aṣọ penpe kan jade lapo mi, mo tutọ si i, mo si fi bo imu mi ki oorun yii ma baa wọ imu mi.
‘‘Ohun ti mo maa ṣakiyesi lẹyin iṣẹju bii marun-un si mẹwaa, ni pe gbogbo awọn to wa ninu ọkọ naa ti lo ti sun lọ fọnfọn, emi nikan ni mi o sun ati awọn ajinigbe yii ti awọn naa ti fi ibomu bo imu wọn.
‘‘Ko pẹ ni mo ri i pe ẹni to je adari awọn eeyan naa wẹyin, lo ba bẹrẹ si i pariwo mọ mi, lo n beere pe ‘iwọ, ko sun ni, ki lo n wo, ki lo n wa’. Igba yii ni mo ti waa mọ pe ọkọ awọn ajinigbe ni mo wọ. Ba a ṣe berẹ si i bara wa sọrọ niyi, mi o gbe oju agan si wọn, bẹẹ ni mi o jẹ ki ohun mi le si wọn. Mo kan n bẹ wọn ni. Mo sọ fun wọn pe foonu ti mo n lo, Galaxy S22, olowo nla ni, owo rẹ to miliọnu kan ati ọọdunrun Naira, wọn le gba a ki wọn ta a ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (800k). Mo ni ki wọn gba kaadi ATM mi ki wọn lọọ gba gbogbo owo to wa nibẹ. Mo tun ni ki wọn gba ṣeeni olowo nla to wa lọrun mi towo rẹ jẹ ọpọlọpọ miliọnu, ṣugbọn wọn ko dahun.
‘‘Wọn ko da mi lohun, wọn ni ibi ti awọn ti maa ja mi ju silẹ ni ibi ti awọn ti maa fi daga gun mi pa, ti awọn si maa ge mi si wẹwẹ.
‘‘Nitori pe wọn ri i pe mo n pariwo, bi wọn ṣẹ ya kuro ni oju ọna niyẹn, wọn waa gba ọna to lọ si abẹ biriiji Adeniji, wọn waa duro nibi abẹ biriiji Adeniji yẹn. Wọn wọ mi ju silẹ, ni wọn ba bẹrẹ si i ṣa mi ladaa ọbẹ ati oniruuru nnkan ija bẹẹ ni wọn bẹrẹ si fi ṣa mi. Ṣugbọn nitori mo jẹ ọmọ Alawọ dudu, emi naa ti dira mi pẹlu agbara eeyan dudu, mi o mu ọrọ ara mi ni kekere latilẹ. Mo duro lọmọkunrin. Eyi lo fa a ti gbogbo ada ati ọbẹ ti wọn fi n ṣa mi ko fi ran mi, ti ko si wọ inu ara mi. Nigba ti wọn ri i pe gbogbo ọbẹ, daga, ada ati oriṣiiriṣiii nnkan ti wọn fi n ṣa mi ko wọle si mi lara, awọn bii mẹta ninu wọn di mi lọrun mu, awọn meji mu apa mi mọlẹ sẹyin, wọn fi ọbẹ si ọrun mi, wọn fẹẹ du u, ṣugbọn ko wọle(Tẹ ẹ ba wo ọrun mi, ẹ maa ri oju apa ọbẹ naa). Mo gbọ ti eyi to jẹ olori wọn n ṣọ fun wọn lẹde Hausa pe ki wọn gbe mi wọnlẹ, ki wọn lo buutu bata ti wọn wọ, ki wọn fi fọ mi lori nitori aṣọ ṣọja ni mẹta ninu wọn wọ. Awọn mẹfa ninu wọn ni wọn di mi mu. Awọn kan di ori mi mu, awọn kan di ẹsẹ mi mu, awọn meji si n lo bata wọn lati gba mi loju, lẹnu ati ni gbogbo ibi to ba ti ba mi. Nigba ti mo ri i pe o ti n rẹ mi ti mo si ti fẹẹ daku, ti iyẹn ba si ti ṣẹlẹ, wọn maa ṣe ohun to wu wọn fun mi. Mo waa ranti pe ọbẹ kan wa ninu baagi mi to wa nilẹẹlẹ, awọn eeyan naa ko ṣakiyesi baagi yii. nigba ti mo raaye mu un ni mo mu ọbẹ yii, mo waa n ju u sọtun-un sosi, o ba ọkan nibi ikun, o ba ọkan lọrun, o ba ọkan nibi oju, ẹjẹ si bẹrẹ si i jade lara wọn. Eyi to jẹ ọga wọn yẹn wa n sọ fun wọn pe ki wọn jẹ ki awọn lọ, ṣebi awọn ṣi ni awọn kan ninu mọto ti wọn n sun ti awọn le lọọ ko jiṣẹ fun awọn to ran awọn. O ni ki wọn fi mi silẹ, ati pe ko si bi mo ṣe le ṣe e ti mi o ni i ku sibi ti mo wa pẹlu gbogbo ohun ti awọn ṣe fun mi.
‘‘Bi gbogbo wọn ṣẹ lọ niyi. Wọn ti fọ imu mi, wọn fọ ẹnu mi, ẹ wo bi mo ṣe n pọ ẹjẹ jade. Oju mi yii gan-an ko gbadun. (Ọkunrin yii hukọ, kiki ẹjẹ ni o si tu jade) Ẹjẹ n jade lati inu mi lọhun-un, mo kan fẹẹ lọọ nu awọn ẹjẹ yii ki n le lọọ gba itọju lọsibitu ni.
‘‘Ẹyin eeyan mi, ootọ ni o. Gbogbo awọn ti mo n sọ nipa wọn yii, awọn eeyan Oke-Ọya ni wọn, awọn eeyan yii ti wọ ipinlẹ Eko, wọn ti wọ Eko o, Ibi Lẹkki, ibi olobiripo (Ikoyi Roundabaount), ni wọn ti gbe mi, nibi Ikoyi, nibi biriiji Ikoyi to lọ si Lẹkki yẹn, niru adugbo to dara bẹẹ yẹn, adugbo nla bẹẹ yẹn.
‘‘Aanu to ṣe mi ni ti awọn eeyan mẹjọ to ku ninu mọto yii, mo mọ pe pipa ni wọn maa pa wọn. Ẹ jọwọ, ẹyin eeyan, ẹ maa kiyesara o. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun to jẹ ki n wa laaye, ọrọ aabo ni orileede yii ti lagbara o’’.