Faith Adebọla, Eko
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ti ni kawọn to n reti lati pade oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu wọn, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu nibi eto idije ita-gbangba lori tẹlifiṣan tabi redio tete lọọ wa nnkan mi-in fi akoko wọn ṣe o, ki wọn si yaa gbọkan wo kuro nidii iru ireti bẹẹ, tori ẹni to ba n wo iṣẹju akan, tọhun yoo pẹ leti omi, o ni Tinubu ko ni i kopa ninu iru idije ati apero bẹẹ, agaga to ba ti jẹ ileeṣẹ tẹlifiṣan ARISE maa kopa tabi ṣagbatẹru ẹ.
Ọrọ yii jade ninu atẹjade kan ti Oludari eto iroyin ati Alukoro fun igbimọ ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ APC, Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga, fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kejila yii.
Atẹjade ọhun ni wọn fi fesi si ikede to wa lori ẹrọ ayelujara, nibi ti wọn ti ṣeto pe Bọla Tinubu yoo kopa ninu ipade idije ita-gbangba ori tẹlifiṣan ARISE lọjọ kẹrin, oṣu Kejila, to wọle de tan yii.
Ọnanuga ni ileeṣẹ naa ko kan sawọn ki wọn too forukọ oludije funpo aarẹ ẹgbẹ awọn sori eto wọn, ati pe iwa bẹẹ ko boju mu, ati pe ọwọ Bọla Tinubu ati eto ipolongo ibo rẹ di ju ko waa lọọ jokoo sibi kan tawọn eeyan yoo ti maa ju ibeere lu u bo ṣe wu wọn, tabi ti yoo lọ sori eto tẹlifiṣan kan ti ko ni i raaye lọ si iru ẹ mi-in ti wọn ba pe e si.
O tẹsiwaju pe: “Niwọn igba ti ko ti si ikanni kankan ti gbogbo oludije ati gbogbo araalu jọ fọwọ si lati jumọ pade fun iru idije ‘beere ki n fun ẹ lesi bẹẹ,’ oludije wa ti n bawọn araalu sọrọ ni taarata latigba ti Aarẹ Buhari ti fi iwe eto ati erongba iṣakoso Tinubu lọlẹ.
“Gẹgẹ ba a ṣe sọ ṣaaju, igbokegbodo to kun fọfọ ni eto ipolongo ibo Aṣiwaju Tinubu, ọwọ rẹ si ha gadigadi, ko tiẹ le raaye lati da ọkan-o-jọkan awọn ileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan ti wọn n pe e pe ko wa sori ikanni wọn lohun, ipinnu wa ni pe ko saaye a n lọọ ṣepade idije tabi ipade itagbangba bẹẹ lọwọ yii, tori a o fẹẹ da awọn kan lohun ka si yan awọn kan nipọsin.
“Titi dasiko yii, o ti to ipade ita-gbangba meje ti Aṣiwaju Bọla Tinubu ti kopa pẹlu awọn lọgaa-lọgaa lawọn ẹka pataki kan, kaakiri agbegbe ati ẹkun kọọkan ni Naijiria la si ti ṣe e, eyi la maa maa ṣe niṣo titi di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Fẹbuari, ọdun 2023.
“A n fi asiko yii rọ ileeṣẹ tẹlifiṣan ARISE lati jawọ ninu fifi orukọ tabi aworan oludije wa polowo ọja wọn.”
Bẹẹ ni Ọnanuga ati APC sọ o.