Gbenga Amos, Ogun
Eemọ lukutu pẹbẹ lọrọ ọhun, bawọn eeyan ṣe n gbọ ọ ni wọn n fọwọ luwọ pe iru ki waa laye da yii, bẹẹ lọpọ eeyan n wọn epe ka-n-di ka-n-di sori gende ẹni ọdun mẹrindinlogoji kan, Sikiru Ajibọla, ti wọn fẹsun kan pe o n ba ọkunrin ẹgbẹ ẹ lo pọ. Wọn lo fipa ki ọmọkunrin ọmọọdun marun-un pere mọlẹ, o si ko ibasun fun un bii pe obinrin ni, afigba tọmọkunrin naa dakẹ mọ ọn labẹ, o ku yan-an-yan-an.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, to fiṣẹlẹ yii to ALAROYEleti ninu atẹjade kan lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii, ni lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, lawọn ọtẹlẹmuyẹ wa ọbayejẹ ọkunrin naa lawaakan, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe e nibi to sa pamọ si niluu Ogijo, nijọba ibilẹ Ṣagamu, ipinlẹ Ogun, nibi tiṣẹlẹ naa ti waye.
Abimbọla ni Alaga ẹgbẹ adugbo Ọlọrunwa Arogbeja Ogijo CDA, lo waa fọrọ naa to awọn leti pe ẹnikan ninu awọn tawọn jọ n gbe adugbo ọhun kẹ ẹ soun leti pe Sikiru ti paayan, ki i si ṣe pe o wulẹ paayan lasan bẹẹ, ibalopọ odi to ṣe fọmọkunrin ọmọọdun marun-un ti wọn forukọ bo laṣiiri lo ṣe yankan-yankan.
Lọgan tọrọ yii detiigbọ DPO teṣan naa, CSP Enatufe Omoh, lo ti paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe ki wọn lọọ wa eeyan to n huwa ẹranko naa kan, ki wọn mu un. Ọlọrun si ṣe e, jagunlabi yii o ti i rin jinna, o ṣẹṣẹ n wa ọna lati sa lọ ni wọn ka a mọ ile kan to sa pamọ si, ni wọn ba gbe e janto.
Ni teṣan, wọn bi i leere boya loootọ lẹsun ti wọn fi kan an, abi wọn purọ mọ ọn ni, o ni wọn o purọ m’oun, ootọ niṣẹlẹ naa waye, amọ ọtọ lohun toun lero, ọtọ ni nnkan to ṣẹlẹ ni o. O loun kan ni koun gbadun ara oun ni, tori oun o ṣẹṣẹ maa ṣeru ẹ, abẹya-kan-naa lo pọ loun, eyi tawọn eleebo n pe ni ‘gee’ (Gay), amọ igba akọkọ toun maa ṣe kinni fun oloogbe yii niyi, o ni loootọ lọmọ naa n kerora nigba toun ki kinni si i niho idi, amọ oun ro pe o n jẹgbadun ẹ ni, afi boun ṣe ri i pe o rọ jọwọrọ mọ oun lọwọ lojiji, to si tutu rinrin, igba toun fi maa yẹ oju ẹ, loun ri i pe o ti ku patapata.
O tun jẹwọ pe ẹsẹkẹsẹ tiṣẹlẹ naa waye loun wo raa-raa-raa, oun sare wa ṣọbiri kan, oun yọ kẹlẹ gbẹlẹ kuṣẹkuṣẹ sẹyinkule ile toun n gbe, ninu igbo ṣuuru kan to wa layiika naa, ibẹ loun bo oku ẹ mọ, oun si mọ pe awo ọrọ naa le lu sita rara.
Awọn ọlọpaa ni ko mu awọn lọ sibi to sinku ọmọ ọhun si, o si kọri sibẹ loootọ, wọn ri oku ọmọ naa, nibi to bo o mọlẹ si bii ẹni sinku aja, wọn si ri ṣọbiri to fi gbẹlẹ ọhun.
Wọn ti fiṣẹlẹ naa to Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, leti, o si ti paṣẹ pe ki wọn ma da afurasi naa duro s’Ogijo mọ, taara ni ki wọn fi i ṣọwọ sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ lẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran abẹle.
O ni wọn gbọdọ tọpinpin iṣẹlẹ yii dori okodoro. O lawọn o ni i jafara lati foju afurasi ọdaju apaayan yii bale-ẹjọ, ki wọn le ṣiwee ofin han an.