Faith Adebọla
Ẹwọn gbere ti n run nimu afurasi ọdaran kan , Ọgbẹni Umaru Isah, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn. Iṣẹ tiṣa ni wọn gba a fun nileewe aladaani kan pe ko maa kọ awọn akẹkọọ ni lẹsinni, amọ wọn ni niṣe lọkunrin yii n mu awọn akẹkọọ-binrin ọhun wọ ileegbọnsẹ ileewe ọhun, aa ni ki wọn ka hijaabu wọn soke tabi ki wọn bọ ọ, wọn lo n fọwọ pa wọn lọmu, o tun n fika ro wọn labẹ, bẹẹ lo si ṣe fun marun-un lara wọn kaṣiiri ẹ too tu, to fi dero ahamọ awọn ọlọpaa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina, SP Gambo Isah, to sọrọ nibi ti wọn ti ṣafihan afurasi ọdaran ọhun lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa sọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii, pe iwadii tawọn ṣe fihan pe awọn tọkunrin naa huwa palapala yii si ju marun-un lọ ninu awọn ọmọ kilaasi rẹ to n kọ niwee.
Wọn ni ni nnkan bii aago mẹwaa owurọ ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla yii, lawọn mẹrin ninu iya awọn ọmọbinrin kan ni kilaasi afurasi naa da rẹi-rẹi lọ si teṣan ọlọpaa, Abilekọ Hussaina Rabe, Basira Umar, Khalid Ibrahim ati Zainab Ibrahim, wọn waa fẹjọ afurasi ọdaran naa sun, wọn lawọn ọmọ awọn ti jẹwọ fawọn pe ologbo ni wọn fẹran ṣọ nileewe awọn, wọn ni niṣe ni tiṣa kilaasi awọn n mu awọn wọ ṣalanga, afi bii ẹni pe ọkunrin naa to wọn sori ila, wọn ni ọjọ ọtọọtọ lo n mu awọn ọmọbinrin naa lọkọọkan, to si n huwa idọti ọhun fawọn ọmọ ọlọmọ.
Nigba ti wọn mu tiṣa arufin yii de teṣan, ti wọn beere bọrọ ṣe jẹ lọwọ ẹ, wọn ni niṣe lo n wolẹ ṣu-un bii atọọle tilẹ mọ ba, o ni loootọ loun huwa aida ọhun. Wọn tun bi i pe bawo lo ṣe ṣẹlẹ, o ni ninu kilaasi toun ti n kọ wọn, yara kotopo kan wa ti wọn kọ sẹgbẹẹ kilaasi ọhun fun ileetura, ibẹ loun maa n mu awọn ọmọbinrin naa wọ lọkọọkan, oun aa bọ hijaabu ti wọn wọ, tabi koun ka a soke, loun aa ba maa fọmu wọn ṣere, oun tun maa n fika ro wọn labẹ.
Wọn beere lọwọ ẹ boya o n ṣe kinni naa fun oogun ọla tabi awure kan ni, o ni rara o, ko si babalawo to ran oun niṣẹ, oun o si ṣe e fun idi mi-in ju pe oun kan fi i mara oun gbona ni, o loun kan ri i pe aṣa naa ti mọ oun lara ni.
Ṣa, tiṣa yii ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ, iwadii si ti n tẹsiwaju lori ọrọ ọhun. Wọn lo maa too bẹrẹ si i kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ tiwadii ba ti pari.